Adewumi Adegoke
Ko jọ pe wahala to n ṣẹlẹ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, nibi ti won ti yọ olori wọn ti wọn dibo yan laarin ọsẹ kan, Gboyega Aribiṣogun, ti wọn si yan Olubunmi Adelugba gẹgẹ bii olori tuntun ti i rodo lọọ mumi o. Idi ni pe aṣofin ti wọn yọ loye naa ti gba ile-ẹjọ lọ, o ni kawọn adajọ bawọn foju ofin wo ọrọ naa, nitori ko yẹ ki wọn yọ oun nipo.
Ọkunrin naa sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu yii fun akọroyin iweeroyin Punch pe oun ti bẹrẹ igbesẹ lati gbe bi awọn aṣofin ẹgbẹ oun ṣẹ yọ oun lọna aitọ naa lọ si kootu, o ni wọn ko gba ọna to bofin mu yọ oun nipo naa. Abisogun ni ofo ọjọ keji ọja ati igbesẹ ti ko le fẹsẹ mulẹ ni bi wọn ṣẹ yọ oun nipo, ti wọn si tun jawee gbele-ẹ fun awọn aṣofin meje mi-in. Ati pe ile-ẹjọ ni yoo bawọn yanju rẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe oun ti gbe awọn ọlọpaa ipinlẹ naa lọ si kootu pẹlu bi wọn ṣe ya bo ileegbimọ naa lọna aitọ, ti wọn si gbakoso ibẹ fun odidi ọjọ mẹfa.
Ọkunrin ọmọ bibi ilu Ijẹsa Iṣu Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, to n ṣoju ẹkun kin-in-ni, ijọba ibilẹ Ikọle yii sọ pe ko si ariyanjiyan ninu pe aọn maa gba ile-ẹjọ lọ lori ọrọ yii. O ni awọn n ṣa iwe aọn jọ ni, bẹẹ laọn si n gba imọran lọwọ aọn agboifinro ki igbesẹ naa too waye. O ni ki ọsẹ ta a wa yii too pari, aọn yoo gbe ọrọ naa lọ si kootu.
Tẹ o ba gbagbe, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn aṣofin bii mẹtadinlogun, ninu awọn mẹẹẹdọgbọn ti wọn wa nile naa, yọ olori ileegbimọ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lọsẹ to kọja, iyẹn lẹyin ti wọn fun aọn meje ninu wọn niwee gbele ẹ fuun ọkan-o-jọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja ni wọn yan Abisogun to jẹ, lakooko ijokoo ile naa to waye ni gbọngan ile aṣofin wọn. Ọnarebu Tajudeen Akingbolu to wa lati ẹkun kin-in-ni ijọba ibilẹ Ariwa Ekiti, lo mu aba lati yan aṣofin naa wa, nigba ti Ọnarebu Adegoke Olajide to n ṣoju ẹkun ijọba ibilẹ Ẹfọn, kin in lẹyin. Bakan naa ni Ọnarebu Bọde Adeoye, to n ṣoju ẹkun keji ijọba ibilẹ Iwọ Oorun ipinlẹ Ekiti yan Arabinrin Olubunmi Adelugba, ti Ọnarebu Ojo Matins toun n ṣoju ijọba ibilẹ Ijero gbe e lẹyin.
Eyi lo fa a tawọn aṣofin naa fi dibo, Aribisọgan ni ibo mẹẹẹdogun, to fi fẹyin Adelugba balẹ.
Ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹside, iyẹn ọjọ keji ti iyansipo naa ṣẹlẹ ni wọn ni awọn kan ti wọn jẹ omọlẹyin gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti o si jẹ pe Adelugba ni wọn n ṣatilẹyin fun ya wọn ile-igbimọ naa, ni wọn ba bẹrẹ wahala, wọn ni awọn tọọgi oloṣelu kan fẹẹ dana sun apa kan ile naa nibi tọrọ ọhun le de.
Awọn agbofinro ni wọn tete lọ sibẹ ti wọn si gbakoso gbogbo agbegbe naa, ni wọn ba ti ile naa pa. Eyi ni ko fi ṣee ṣe fun awọn aṣofin naa lati jokoo, ti onikaluku awọn oṣiṣẹ si gba ile wọn lọ. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, nigba ti awọn aṣofin naa tun pade, ti wọn si yọ Aribisọgan, ti wọn fi Adelugba rọpo rẹ.