Ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologboo adigunjale meji to n yọ wọn lẹnu n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi adigunjale meji kan, Akeem Suleiman ati Sọdiq Abdulkareem, ẹni ọdun mẹẹẹdogbọn, ti wọn lo maa n figba gbogbo daamu awọn olugbe Akérébíata, wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn maa n ja awọn araalu lole nigba gbogbo nipaṣẹ fifọ ṣọọbu. Ṣọọbu obinrin Gírígísù Rahamatallahi ni wọn lọọ fọ tọwọ agbofinro fi tẹ wọn.

ALAROYE gbọ pe ninu oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni ọwọ palaba awọn afurasi mejeeji ṣẹgi lasiko ti wọn lọọ ja obinrin yii lole. Wọn lọọ fọ ṣọọbu obìnrin naa, wọn si ji owo ati dukia gbe lọ, ṣugbọn ọwọ awọn araadugbo tẹ ẹ, wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.

Agbefọba, Ogbole Arram, ni ọjọ ti pẹ ti ti awọn afurasi ọhun atawọn yooku wọn ti maa n ja araalu lole, eyi to ta ko iwe ofin ilẹ wa. Bakan naa lo ni awọn afurasi mejeeji jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn si ti ṣeku pa ọpọ alaiṣẹ. Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi han, ẹgbẹ Aiye ni wọn n ṣe, ti wọn si ti bẹrẹ lati ọdun 2020.

Agbefọba ti gbe iwe ẹjọ awọn afurasi yii lọ siwaju kootu Majisireeti kan niluu Ilọrin, nibi ti wọn yoo ti lọọ ṣalaye ohun to sun wọn de ibi iṣẹ ole jija fun adajọ.

Leave a Reply