Faith Adebọla
Yoruba bọ, wọn ni ikun n jọgẹdẹ, ikun n redi, ikun o mọ pe ohun to dun ni i pa ni. Owe yii lo wọ ọrọ gende ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Taofeek Isah, ile-ẹjọ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun un, ki wọn so o rọ titi tẹmii yoo fi bọ lara ẹ, latari pe o jẹbi ẹsun fifipa ba ọmọdebinrin ẹni ogun ọdun kan, Blessing Ezekiel, laṣepọ pẹlu inira.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun yii, ni ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Auchi, nipinlẹ Edo, pa iwe de lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan ọdaran yii atawọn ọrẹ ẹ mẹta mi-in ti wọn jọ lọwọ ninu iwakiwa ọhun. Orukọ awọn yooku ni Godwin Adeyẹmi, Jeremiah Okamudu ati ẹnikan to ni Miracle loun n jẹ.
Awọn ẹsun mi-in ti wọn fi kan wọn ni pe o lo egboogi oloro fun ọmọọlọmọ lodi si ifẹ-inu ẹ, wọn ji Blessing gbe, wọn si tun ṣe e leṣe.
Amofin Clement Eseigbe, to jẹ agbẹjọro ijọba, to si ṣoju fun olupẹjọ, iyẹn ẹka to n ri si eto idajọ nipinlẹ naa ṣalaye ni kootu pe iwadii fidi ẹ mulẹ pe loootọ lawọn ọdaran yii huwa ika ọhun lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, lagbegbe Okpella nijọba ibilẹ Ila-Oorun Etsako, ipinlẹ Edo.
O ni iwa ọdaju ti ko ṣee gbọ seti ni wọn hu, tori lẹyin ti wọn dọdẹ ọmọbinrin naa, ti wọn ji i gbe wọgbo, wọn fi pẹtẹpẹtẹ ada ati igi lu u nilukulu, lẹyin eyi ni wọn da a dubulẹ, ti wọn si fipa ba a sun lọkọọkan. O ni niṣe lawọn eleṣu ẹda yii to tọọnu lori ọmọbinrin ọhun, igba ti wọn si tun ṣetan, wọn bu ata gbigbẹ si i loju ara. Gbogbo bi ọmọbinrin naa ṣe n jẹrora, to n kigbe oro, ẹrin ni wọn n fi i rin, nibi ti iwa-ibi jaraaba wọn de. Ọlọrun ni ko si jẹ kọmọ naa ku sinu igbo naa ki aṣiri wọn too pada tu.
O ni iwa ti wọn hu ọhun ta ko isọri kẹrin ati ikarun-un, apa ki-in-ni, abala B, ati isọri kẹẹẹdọgbọn, apa ki-in-ni iwe ofin to ka hihuwa ọdaran sọmọlakeji-ẹni leewọ nipinlẹ ọhun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Philip Imoedemhe ni gbogbo ẹri ati ẹlẹrii ti olupẹjọ ko wa sile-ẹjọ ti fidi awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ yii mulẹ, o si kan saara sawọn agbefọba fun iwadii ijinlẹ ti wọn ṣe lati foju ododo han.
Adajọ bẹnu atẹ lu awọn ọdaran wọnyi, o ni iwa ọbayejẹ, iwa ika ati odoro gbaa ni wọn hu, o ni ootọ ni ọrọ ti wọn n sọ pe bi ile kan ba n toro, ọmọ ale ibẹ ni o ti i dagba, o niwa to n da ile ru, to n da ilu ru, to si n ṣakoba fun awujọ ni wọn hu, tori ẹ, iru wọn o gbọdọ tun maa rin yan fanda niluu mọ, ki wọn lọọ kọgbọn lẹwọn lo daa.
Lo ba ni ki wọn sọ awọn ọrẹ mẹta ti wọn kun Taofeek lọwọ sẹwọn, ẹni tẹwọn rẹ kere ju lo sọ sọdun mẹrin, ẹni ti tiẹ pọ ju yoo lo ọdun mọkandinlogun ni keremọnje.
Ni ti Taofeek, olori wọn, wọn loun maa lọọ kọgbọn ni saare ni tiẹ ni. Adajọ ni ki wọn gbẹmi lẹnu ẹ, tori iwa apaayan lo hu, idajọ tiẹ ko si la tẹwọn lọ, iku lo tọ si i.
Eeyan o le gbọjọ iku ẹ ko dunnu, niṣe ni Taofeek bu sẹkun gbaragada ni kootu, o jọ pe ko reti pe patapata leegun i daṣọ bori ni wọn maa ṣe ọrọ ọhun, o fomije rawọ ẹbẹ sadajọ, ṣugbọn ẹpa o boro mọ, okete rẹ ti degba alatẹ ko too kawọ iboosi leri.