Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Beeyan ko ba lọkan akin, ko ni i le wo awọn eeyan tijamba mọto kan ṣẹlẹ si laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu keje yii, nibi ti ẹya ara eeyan ti n ja butẹ nilẹẹlẹ, ti ori ti fọ patapata, ti eeyan marun-un ku lẹsẹkẹsẹ. Ni marosẹ Eko s’Ibadan ni!
Ọgangan Ayetoro si Indomie, niṣẹlẹ yii ti waye loju ọna ẹsipirẹsi naa. Nnkan bii aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju laaarọ ni wahala yii ṣẹlẹ. Ọga ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, ṣalaye pe awọn ọkọ meji ti asidẹnti naa ṣẹlẹ si ni bọọsi Toyota ti nọmba ẹ jẹ SPR 373 XA, ati tirela ti nọmba tiẹ jẹ GGE 468 XX.
Umar ṣalaye pe eeyan mẹsan-an ni ijamba yii kan, ọkunrin mẹfa, obinrin mẹta. Ọga FRSC Ogun naa sọ pe ijamba to ṣee dena ẹ lawọn awakọ yii jẹ ko ṣẹlẹ, nitori ere buruku ti awakọ bọọsi Toyota n sa lo jẹ ko lọọ kọ lu tirela to n bọ, to ko si i lẹnu koro tiyẹn fi run un pa.
Eeyan marun-un lo ku loju-ẹsẹ gẹgẹ bi Kọmandanti Umar ṣe wi, awọn mẹrin si fara pa gidi to jẹ ọsibitu Idẹra lawọn gbe wọn lọ, ni Ṣagamu, ibẹ naa lo ni awọn ko oku awọn to ṣalaisi si.
Gẹgẹ bi akọsilẹ iwe tawọn ero ọkọ bọọsi naa kọ fawọn ọlọkọ ki wọn too kuro ni gareeji (manifest), ilu Eko lọkọ bọọsi naa ti kuro, Eket, nipinlẹ Akwa Ibom, lo si n lọ. Wọn ko ti i rin ida kan irin ajo naa ti wahala fi de, ti oku eeyan to lọ bẹẹrẹbẹ.
Orukọ eeyan mẹjọ ree ninu awọn mẹsan-an to wa ninu bọọsi Toyota naa: Maria Innocent, Emmanuel Evans, Esther Umoh, Esther Bradfield, Adisa Kamiludeen, Ernest Solomon, David Kenneth ati Godspower Amaye. O jọ pe ẹni kẹsan-an ko kọrukọ tiẹ sinu iwe ti wọn kọ ni gareeji naa.
Ṣa, FRSC ati TRACE lawọn ba awọn eeyan to padanu ẹni wọn kẹdun lori iṣẹlẹ yii, wọn rọ wọn ki wọn lọ si kọmandi FRSC to wa ni Mowe lati gbọ alaye si i nipa iṣẹlẹ yii, ki wọn si le gba ẹru awọn eeyan wọn tawọn ba nibudo ijamba ọhun.