Emi ni ma a ṣaaju ifẹhonu han ti ijọba Tinubu ko ba ṣe daadaa – Oluwoo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti i ṣe Oluwoo ti ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, ti kede pe oun loun yoo ṣiwaju ifẹhonu han ti ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ko ba ṣe daadaa lori aleefa.
O ni loootọ ni gbogbo igbesẹ Tinubu ti n fi han pe ireti wa fun orileede yii, ṣugbọn o gbọdọ mura si i, ko si mojuto awọn ti wọn n ba a ṣejọba lati huwa to tọ.
Nibi irun Yidi ọdun itunu-aawẹ to waye niluu Iwo lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Ọba Akanbi ti sọ pe a-jẹ-ẹ-jẹ-tan ni asiko ti Aarẹ Tinubu n lo lọwọ yii, gbogbo oju lo si wa lara rẹ.
O ni Tinubu ko ni ọna miiran ju pe ko ṣe daadaa fun awọn eeyan orileede yii lọ, nitori tijọba rẹ ko ba ṣe daadaa, a jẹ pe ko tun si ireti mọ fun orileede Naijiria niyẹn.
Oluwoo sọ siwaju pe awọn ọmọ orileede ti n ri ipa rere ijọba rẹ nitori ko ti i si Aarẹ ti owo dọla lọ soke lasiko tirẹ, to si tun pada walẹ, ṣugbọn o tun gbọdọ jara mọ igbesẹ ti yoo mu ki igbeaye rọrun si i, lai jẹ bẹẹ, oun yoo ṣaaju ifẹhonu han nipa ijọba rẹ.
Lori eto aabo, Oluwoo sọ pe ijọba nilo lati gba awọn eeyan si iṣẹ ọlọpaa si i, o ni ko si bi ọlọpaa ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ṣe fẹẹ maa ṣọ awọn eeyan to din diẹ ni ọọdunrun miliọnu ti nnkan yoo lọ deede.
O ni orileede Naijria nilo, o kere tan, awọn ọlọpaa miliọnu mẹwaa fun eto aabo lorigun mẹrẹẹrin ilẹ wa, eleyii yoo si tun jẹ ọna ipese iṣẹ fun awọn ọdọ.
Bakan naa lo tun rọ ijọba lati fun awọn ori-ade ni ojuṣe ninu ofin orileede yii, o ni eleyii nikan ni yoo din wahala eto aabo ku, nitori awọn ọba ni wọn sun mọ awọn araalu ju lọ, ti wọn si mọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ.
Oluwoo ke si awọn Musulumi lati ri i daju pe wọn tẹsiwaju ninu iwa iṣẹ oore ati ifarada ti wọn n hu ninu aawẹ Ramadan, ki wọn si tẹsiwaju nipa gbigbadura fun orileede Naijiria.