Paul binu tan, o pa Fúlàní to fi maalu jẹ ọmọ rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

O jọ pe fitina ojoojumọ tawọn Fulani onimaaluu n fun ọkunrin agbẹ ẹya Tiv kan, Paul Amaech, lo mu ko ṣi inu bí, to sí pa Fúlàní to fi maaluu jẹ gbogbo oko to da naa. Ṣugbọn ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nile, pẹlu bawọn ọlọpaa iipinlẹ Ọṣun ṣe fọwọ ofin mu omokunrin naa lori ẹsun pe o pa ọkunrin Fulani darandaran kan sinu oko rẹ.

Abule Talamu ni Agọ Owu Farm Settlement, ni Orile-Owu, nipinlẹ Ọṣun, niṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe ọsẹ meji sẹyin ni maaluu ọkunrin Fulani yii lọ sinu oko Paul, to si jẹ nnkan-oko rẹ, eleyii to bi i ninu pupọ.

Ṣugbọn ṣadeede lawọn ara abule ba oku ọkunrin Fulani naa ninu oko Paul lọjọ Tọsidee, Seriki Fulani ti Ijẹbu Igbo, si lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa Orilẹ-Owu leti.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ ajọ sifu difẹnsi gbe oku Fulani naa lọ ni wọn bẹrẹ iwadii lori iku to pa ọmọkunrin naa, ti wọn si mu Paul to ni oko yii lati fọrọ wa a lẹnu wo.

Amọ agbẹnusọ fun ajọ yii nipinlẹ Ọṣun, Kẹhinde Adeleke, ṣalaye pe ki i ṣe oloogbe yiii nikan lo wa ninu igbo lasiko ti Paul pa a.

O ni fulani miiran ti wọn jọ n da maaluu kaakiri lasiko iṣẹlẹ naa lo yọju si agọ ọlọpaa, to si naka si Paul pe oun lo pa ẹnikeji oun.

Adeleke sọ siwaju pe lẹyin ti akara tu sepo ni Paul naa jẹwọ nnkan to ṣe, iwadii ṣi n tẹ siwaju.