Ṣe Emefiele yo bọ ninu wahala to wa yii ṣa, eyi lohun ti adajọ ni ki wọn ṣe fun un

Adewale Adeoye

Ba a ba reeyan to sọ pe ọga agba banki apapọ orileede yii tẹlẹ, Ọgbẹni Godwin Emefiele, maa tete bọ ninu wahala nla ti ko ara rẹ si, o n purọ ni, nitori pe aipẹ yii ni adajọ agba ile-ẹjọ giga kan to n gbọ ẹjọ rẹ l’Ekoo, paṣẹ pe ki wọn gba awọn dukia olowo iyebiye kan ti wọn lo fọna eru ko jọ lasiko to fi wa nipo aṣẹ lọwọ rẹ, ki wọn ko o fun ijọba apapọ nilẹ wa.

Iwaju Onidaajọ Dẹinde Dipẹolu, tile-ẹjọ giga kan to wa l’Ekoo, ni wọn foju Emefiele ba lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Awọn dukia olowo iyebiye ti wọn gba lọwọ Emefiele ni ipin idokoowo to ni sileeṣẹ kan ti wọn n pe ni ‘Queensdorf Global Fund Limited Trust’ ati miliọnu meji dọla owo ilẹ okeere.

Yatọ si eyi, adajọ naa tun ni ki wọn gba awọn ile ati ilẹ olowo iyebiye kan to wa lagbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko, lọwọ Emefiele.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe Emefiele ko le fidi ibi gan-an to ti ri owo to fi ra awọn dukia naa rẹ mulẹ fun ile-ẹjọ. Wọn ni owo-oṣu rẹ lasiko to fi n ṣiṣẹ ni banki Zenith, ati lasiko to fi jẹ ọga agba ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa ko to lati fi ra awọn dukia olowo iyebiye ti wọn ba lọwọ rẹ. Ṣa o, agbẹjọro Emefiele, Ọgbẹni Ọlalekan Ojo SAN, ti rọ adajọ pe ko ṣiju aanu wo onibaara oun, ko ma ṣe paṣẹ pe ki ijọba apapọ gbẹsẹ le dukia Emefiele.

Leave a Reply