Ṣẹgun Oni ti darapọ pọ mọ SDP l’Ekiti, o ni oludije mẹrin ninu ẹgbẹ APC lo maa tẹle oun

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Oloye Segun Oni, ti fi ẹgbẹ PDP silẹ, o ti kede pe ẹgbẹ SDP (Social Democratic Party) ni oun ti fẹẹ dije ninu eto idibo to n bọ lọna.

Oloṣelu naa to jẹ ọmọ bibi ilu Ifaki-Ekiti, sọ pe mẹrin ninu awọn oludije ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ ti wọn binu lo maa tẹle oun lọ sinu ẹgbẹ tuntun ti oun n lọ yii.

Oni salaye pe idi pataki toun fi kuro ni PDP ni pe ki oun ma ṣe dojuti awọn alatilẹyin oun, ati ki oun le dije ninu eto idibo gomina ti yoo waye ninu oṣun kẹfa, ọdun yii.

Oni sọ pe awọn oludije mẹrin ti wọn fẹ tẹle oun naa ni wọn pe orukọ won ni “Ẹgbẹ alatunṣe” to jẹ igun kan ninu ẹgbẹ APC, ti wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ SWAGA, iyẹn ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ipolongo fun Aṣiwaju Bọla Tinubu lati di aarẹ Naijiria.

Ọkunrin naa to sọrọ lori ẹrọ redio aladaani kan nipinlẹ Ekiti sọ pe oun ti pari gbogbo eto lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ alatunṣe naa lati le jawe olubori lasiko eto idibo gomina to n bọ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa.

Oni ṣalaye siwaju si i pe oun ti ṣejọba ri l’Ekiti, ti oun si ti kọ orukọ ara oun silẹ ni rere, ati pe oun ṣetan lati ṣiṣẹ fun itẹsiwaju ipinlẹ Ekiti.

 

O rọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti pe ki wọn ma ṣe jẹ ki ẹgbẹ APC ra ibo lọwọ wọn, tabi lo ọna miiran lati gba ẹtọ wọn lọwọ wọn lasiko idibo naa. O ṣeleri pe oun yoo ṣe ohun gbogbo lati da ẹgbẹ Onigbaalẹ duro lati ra ibo awọn oludibo lasiko eto idibo naa.

Nigba to n sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ekiti, o ni ẹgbẹ naa ko bọwọ fun ofin ati Ilana to rọ mọ eto idibo abẹle naa. O fi kun un pe aisootọ ati ododo lasiko naa lo jẹ idi kan pataki toun ṣe fi ẹgbẹ Alaburẹla silẹ, ti oun ṣe gba inu ẹgbẹ tuntun miiran lọ.

Oni ti ṣe gomina ipinlẹ Ekiti lọdun 2007 si 2010, o padanu eto idibo abẹle ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, pẹlu bi wọn ṣe kede alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹ, Ọnarebu Bisi Kọlawọle.

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ bi ẹgbẹ SDP yoo ṣe jawe olubori pẹlu bii eto idibo ṣe ku oṣu mẹrin, Oloye Oni sọ pe oun ti ṣe gbogbo eto pẹlu awọn oludije miiran ninu ẹgbẹ APC ati PDP lati jawe olubori lasiko idibo naa.

Ṣugbọn nigba to n fesi si ọrọ Ṣẹgun Oni pe ẹgbẹ SWAGA yoo darapọ mọ oun, Oludari ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti, Oloye Bamigboye Adegoroye, sọ pe irọ patapata ni.

O ṣalaye pe Oni ni ki i ṣe oloootọ oloṣelu ti ẹgbẹ SWAGA ti oun n ṣe akoso re lẹ darapọ mọ, o ṣalaye pe ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin lo sọ pe oun fẹẹ lọ ẹgbẹ APGA, koo too tun pada lọ si ẹgbẹ SDP.

O fi kun un pe gbogbo igbesẹ wọnyi fihan pe Sẹgun Oni ki i ṣe oloṣelu kan ti eeyan le tẹle lọ inu ẹgbẹ kankan tabi to ṣe e duro ti lasiko idibo.

Leave a Reply