Ṣẹgun Oni wọ alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti lọ sile-ẹjọ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

 Fun bo ṣe tapa si asẹ ile-ẹjọ, oludije fun ipo gomina eto idibo oṣu Kẹfa, ọdun yii, ninu ẹgbẹ Ẹlẹṣin (SDP) nipinlẹ Ekiti,  Oloye Ṣẹgun Oni, ti wọ alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ naa, Dokita Adeniran Tẹla, lọ sile-ẹjọ fun titapa sofin kootu to n gbọ ẹsun lori eto idibo naa.

Oni to jẹ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, sọ ninu iwe ẹsun naa pe alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti ko bọwọ fun ofin ile-ẹjọ naa pẹlu bi ko ṣe faaye gba oun ati ẹgbẹ oṣelu oun lati ṣe ayẹwo si awọn ohun eelo ti wọn lo lakooko eto idibo naa gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe paṣẹ.

Ṣaaju lo ti kọkọ kọ iwe ifẹhonuhan kan lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, si alaga gbogbogboo ajọ eleto idibo, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu, nibi to ti fẹsun kan Dokita Tẹla ati awọn oṣiṣẹ ajọ naa l’Ekiti pe wọn fẹẹ ṣe oun gbogbo lati ri i pe wọn doju igbẹjọ ti oun pe ta ko esi idibo naa bolẹ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nibi ipade oniroyin kan to pe lopin ọsẹ to kọja, agbẹjọro to ṣaaju ikọ awọn lọọya rẹ, Ọgbẹni Owoṣeeni Ajayi, sọ pe awọn gbe igbesẹ lati pe alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti lẹjọ pẹlu bo ṣe sọ fun Ṣẹgun Oni pe ko lọọ gba aṣẹ lati olu ileeṣẹ ajọ naa l’Abuja ko too le ṣayẹwo si oun eelo eto idibo naa.

Ajayi sọ pe eleyi jẹ ọna titẹ ofin ile-ẹjọ ati titẹ ofin loju mọlẹ,  o fi kun un pe gbogbo iwe to yẹ ki onibaara oun ko silẹ lo ti ko silẹ ni kootu, o ni gbogbo eto idibo ti wọn ti ṣe nipinlẹ naa sẹyin, ipinlẹ Ekiti ni wọn ti ṣe ayẹwo si oun eelo ti wọn lo nipinlẹ naa, ki i ṣe ilu Abuja ni wọn ti lọọ ṣe e.

“O jẹ oun iyalẹnu fun wa nitori pe iwe kan ti alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti kọ lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, pe ka lọ si olu ileeṣẹ wọn to wa l’Abuja ka too le ṣe ayẹwo si oun eelo idibo naa lẹyin ti ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ eto idibo ti fun wa ni aṣẹ lati ṣe ayẹwo naa.

“Lati igba ti ijọba awa-ara-wa ti pada si orilẹ ede Naijiria, ko si ẹgbẹ kan to lọọ ṣe ayẹwo si oun eelo idibo ni ilu Abuja, eleyii jẹ ọna lati tẹ ofin loju, eleyii fihan pe alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Ekiti ko bọwọ fun ofin ile-ẹjọ. Ẹgbẹ oṣelu alatako naa ni ẹtọ tiwọn labẹ ofin ati ilana oṣelu awa-ara-wa.

Bakan naa ni Ajayi ṣalaye bi alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti, Dokita Adeniran Tẹla, ṣe fẹ da oju igbẹjọ naa bolẹ ninu iwe ẹsun kan ti agbẹjọro naa kọ sí ajọ eleto idibo.

O ke pe ajọ naa pe ki wọn tete ṣe atunṣe, nipa bayii, orukọ rere ti ajọ naa ti ni ko ni i le bajẹ.

Nigba to n fesi si ọrọ naa, Alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Ekiti, Dokita Adeniran Tẹla, sọ pe oun ko ni ohun kankan lati bẹru lori ẹjọ ti wọn pe oun naa, o ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti ko gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan,  o ni ki ẹgbẹ Ẹlẹṣin jawọ lati maa pa irọ mọ oṣiṣẹ ajọ eleto idibo naa.

Leave a Reply