Ṣẹgun to ṣẹṣẹ tẹwọn de ti tun fẹẹ pada sibẹ bayii o

Iyiade Oluṣẹyẹ

Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ṣẹgun nibi to ti n ji iṣu oniṣu wa ninu oko kan lagbegbe Fagun niluu Ondo.

Gẹgẹ bi ohun t’ALAROYE gbọ, ọjọ pẹ ti ọkunrin ọmọ bibi Ire ni ipinlẹ Ọsun naa ti n ja awọn eeyan agbegbe ọhun lole ko too ṣe eyi tọwọ ti tẹ ẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.

Obinrin araadugbo kan to ka ọkunrin yii mọ ibi to ti n wa iṣu ninu oko ẹnikan lalẹ ọjọ naa lo sare pe ọkọ rẹ lori foonu lati tete maa bọ ko waa wo ohun toju oun ri.

Tọkọ-taya naa ko fu ole yii lara, ṣe ni wọn sapamọ sibi kan titi ti oloko funrarẹ ti wọn ranṣẹ pe fi de, lẹyin eyi ni wọn too pariwo ole ti wọn si wa gbogbo ọna tọwọ fi tẹ ẹ.

Wọn ni Ṣẹgun jẹwọ nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ni teṣan awọn ọlọpaa Fagun ti wọn mu un lọ pe o pẹ diẹ toun ti n ji awọn ire awọn oko ti wọn n da si agbegbe naa.

Ọkan ninu awọn ọlọpaa tesan ọhun sọ fun wa pe, ko tii pẹ rara ti Ṣẹgun tẹwọn de bakan naa lo ni lati bii ọjọ diẹ sẹyin lawọn tun ti n wa a lori ọkan-o-jọkan awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni awọn tọkọtaya kan to n gbe lagbegbe Sabo niluu Ondo ni wọn n ra awọn ẹru ole naa lọwọ oun.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti n wa gbogbo ọna lati fi panpẹ ofin gbe awọn onibaara rẹ ṣugbọn ti wọn ko ti i ri wọn mu titi di asiko táa fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

 

 

Leave a Reply