Lati fopin sì oríṣiiríṣii wahala tó ní ṣẹlẹ nínú ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Gomina Ṣeyi Makinde ti sọ pe yóò dara ti Ọ̀túnba Gbenga Daniel ba le máa ṣàkóso ẹgbẹ ọhun.
Nibi ipade ti Makinde, gomina ipinlẹ Ọ̀yọ́, ṣe pẹlu Gbenga Daniel, gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, nile ẹ niluu Sagamu lọrọ ọhun ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee.
Koko ohun to fa iṣẹ nla ti wọn fẹẹ gbe fún ọkunrin oloṣelu yii ni lati wa ojuutu sí bí ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe pin yẹlẹyẹlẹ bayii nipinlẹ Ogun. Bo tilẹ jẹ pe Gbenga Daniel ti sọ ọ tẹlẹ pé òun fẹẹ yẹra fún oṣelu, sibẹ oun ti Makinde atawọn àgbààgbà oloṣelu ninu ẹgbẹ PDP bíi Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla atawọn kan nilẹ Yoruba n wa bayii ni bi yóò ṣe gba ipò olórí ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun.
Makinde sọ pe Ọtunba Daniel lo yẹ nipo ọhun latari awọn àmúyẹ to ni, ati pe oun yii kan naa lo le da alaafia pada saarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti wọn ti pin sí oríṣii mẹta bayii l’Ogun.
Makinde loun mọ ipa nla to ko lori bi wọn ṣe fa oun kalẹ nipinlẹ Ọyọ lati dije dupo gomina, ati pe iru eeyan ti ẹnu ẹ tolẹ dáadáa bẹẹ ni yóò lè dari ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun, ti alaafia yoo si jọba pada laarin awọn ọmọ ẹgbẹ.
Daniel sọ ni tiẹ pe ẹgbẹ oṣelu kan to dara ju fun awọn ọmọ Naijiria nipinlẹ Ogun ni PDP n ṣe.
Bakan naa lo gba ẹgbẹ yìí níyànjú láti ṣatunto iru àwọn èèyàn tí yóò máa darí ẹgbẹ ọhun gẹgẹ bii ọna abayọri fún ẹgbẹ naa.