Lẹyin wahala buruku to bẹ silẹ niluu Ibadan laarin awọn Hausa/ Fulani atawọn Yoruba lagbegbe Ṣaṣa, Gomina Ṣeyi Makinde ati gomina bii mẹrin lati ilẹ Hausa lọhun-un ti yọju sibẹ lati pẹtu si awọn to n binu ninu.
Lẹyin ọjọ karun-un ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni Ṣeyi Makinde atawọn gomina wọnyi; Sani Bello lati ipinlẹ Niger, Bello Matawalle, lati Zamfara, Abubakar Bagudu, lati Kebbi ati Abdullahi Ganduje ti Kano, ti lọọ ba awọn Hausa ati Yoruba sọrọ laduugbo Ṣaṣa, nijọba ibilẹ Akinyẹle, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
Nibi ipade ita gbangba ọhun, eyi to gba wọn bii wakati meji ni wọn ti rọ awọn eeyan naa lati gba alaafia laaye. Wọn lo pẹ ti wọn ti n ba ara wọn gbe, ati pe aigbọra-ẹni-ye lo ṣokunfa wahala ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ti wahala ọhun bẹ silẹ.
Makinde ninu sọ pe Hausa ti n fẹ Yoruba lagbegbe naa, bẹẹ lawọn Yoruba paapaa ti n ṣọkọ Hausa daadaa, fun idi eyi, ki wọn gbagbe wahala, ki wọn si maa ba ara wọn ṣe lọ.
Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ẹnikẹni sibẹ, ko ṣai mẹnuba eto igbeyawo to waye laarin ọmọ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Oloogbe Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, ati Gomina Ganduje, bẹẹ lo fi kun ọrọ ẹ pe ko sohun to dara bii ki wọn gba alaafia laaye lawujọ.
Bagudu ni tiẹ ṣeleri pe ajọ awọn gomina yoo kun Gomina Ṣeyi Makinde lọwọ lori eto iranwọ to fẹẹ ṣe fawọn to padanu rẹpẹtẹ ninu iṣẹlẹ ọhun.