Monisọla Saka
Owe a ki i sin baba ka tun sin ọmọ ni ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ẹka ti ipinlẹ Eko, n pa pẹlu bi wọn ṣe fi aidunnu wọn han si ariwo to n lọ kiri igboro bayii pe awọn kan ti n fọwọ si i lọtun-losi pe ki Ṣeyi, iyẹn ọmọ Aarẹ Bọla Tinubu maa mura lati di gomina ipinlẹ Eko. Ẹgbẹ yii ni gbogbo ọna lawọn atawọn araalu maa gba lati kọ igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe lati sọ Ṣeyidi gomina nipinlẹ Eko.
Ẹgbẹ PDP fi atẹjade yii sita latari ontẹ lọtun-un losi tawọn ẹgbẹ kan n jan Ṣeyi Tinubu, pe oun lawọn fọwọ si lati gba ipo iṣakoso ipinlẹ ọhun lẹyin Gomina Babajide Sanwo-Olu.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni agbarijọpọ awọn olori ọdọ nilẹ Naijiria, Coalition of Nigerian Youth Leaders, ti kọkọ fi atẹjade ibi ti wọn ti fontẹ jan Ṣeyi lati dupo gomina ipinlẹ Eko jade nibi ipade ti wọn ṣe niluu Owerri, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Imo, sita.
Bakan naa tun ni awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni ọrẹ Ṣeyi, ‘Friends of Ṣeyi Tinubu’, naa fọwọ si i pe ko di gomina ipinlẹ Eko lasiko ibo to n bọ. Wọn ni adari to ni afojusun rere, to ni laakaye, oju aanu ati ọgbọn teeyan fi n ṣe nnkan yanju ni ọmọ Aarẹ naa n ṣe.
Amọ ọrọ naa ko ta lọdọ awọn eeyan kan. Lara iru awọn eeyan to bu ẹnu atẹ lu iru aba bẹẹ ni Ọgbẹni Hakeem Amọdẹ, ti i ṣe agbẹnusọ ẹgbẹ PDP nipinlẹ Eko.
Lasiko to n ba akọroyin Punch sọrọ, Amọdẹ sọ pe awọn ko le gba.
“Ipinlẹ Eko ko ni i sin in”.
O ni oun ko mọ pe ipo gomina ti tun di oye idile ti wọn n jogun ẹ, o ni ki i ṣe nnkan to bojumu fun ọmọ lati jogun ipo lọwọ baba ẹ.
“Ipo gomina ki i ṣe ẹbun”. Amọdẹ ni to ba jẹ gbogbo iru ete ti wọn lo nipinlẹ Edo ati Ondo, lasiko ibo ti wọn ṣẹṣẹ ṣe kọja yii ni ẹgbẹ APC fẹẹ lo l’Ekoo, awọn yoo gbena woju wọn, nitori awọn ko ni i gba.
O ni o yẹ ki a ranti pe pupọ awọn eeyan ipinlẹ Eko ni wọn ko dibo fun Tinubu lasiko ibo Aarẹ to kọja, o ni eyi n tọka si pe wọn ko le ti ọmọ ẹ lẹyin to ba gbegba ibo gomina ni.
Bo tilẹ jẹ pe Agbẹnusọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Eko, Ṣẹyẹ Ọladẹjọ, ti ni irọ to jinna si ootọ lọrọ naa, pe ọrọ ibo 2027 niru akoko ta a wa yii ti ya ju. O sọ pe, “O ti ya ju lati maa sọrọ eto idibo ọdun 2027 nisinyii. Ohun to yẹ ki a ṣe ni lati gbaruku ti gomina wa ati Aarẹ to n dari wa lọwọ, lati le ni idagbasoke”.
Ẹgbẹ awọn ọdọ ti wọn jẹ ògidì ọmọ Eko ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ naa pẹlu. Wọn ni mọlẹbi Tinubu kankan ko tun gbọdọ gba ipo gomina Eko mọ. Awọn ẹgbẹ yii ni o ti waa to gẹẹ, awọn ko faaye gba atọhunrinwa lati wa maa ṣejọba lori awọn nipinlẹ Eko mọ.
Wọn ni aaye ko si nipinlẹ Eko, ṣugbọn aaye wa fun Ṣeyi Tinubu lati lọọ dupo gomina nipinlẹ Ọṣun to jẹ ipinlẹ abinibi rẹ, tabi ko lọ sipinlẹ Imo, nibi ti awọn to jan an lontẹ n gbe, ki wọn si fa a kalẹ ko ṣe gomina wọn nibẹ lẹyin ti isakooso ẹni to wa nibẹ bayii ba pari.