Ṣẹyin naa ti gbọ: Bẹ ẹ ba fẹẹ lẹ taisi sile yin l’Ekoo, ẹ gbọdọ gbaṣẹ lọdọ ijọba

Adewale Adeoye

Ni bayii, awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe o ṣe pataki pupọ fawọn to n kọle tuntun lọwọ tabi ti wọn fẹẹ ṣatunṣe lati kọkọ gbaṣẹ lọwọ ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko, iyẹn ‘Lagos State Physical Planning Permit Authority’ (LASPPPA) iyẹn ajọ to n ṣamojuto eto ikọle laarin ilu Eko, ki wọn si gbawe aṣẹ lati ọdọ ijọba ko too di pe wọn bẹrẹ si i kọle wọn, koda, o ti di dandan fawọn eeyan ipinlẹ Eko lati gbawee aṣẹ lọdọ ajọ naa bayii bi wọn ba fẹẹ ṣatunṣe sara awọn ile ti wọn ti n gbe tẹlẹ. Wọn gbọdọ gbawe aṣẹ bi wọn ba fẹẹ lẹ taisi silẹ ile ti wọn ti n gbe tẹlẹ.

ALAROYE gbọ pe lati ọdun 2019 nijọba ipinlẹ Eko ti ṣe awọn ofin ọhun, ṣugbọn tawọn eeyan ko mu un lo rara. Ni bayii, wọn lo ti di dandan  pe ki wọn lọọ gba iyọnda lọwọ ajọ LASPPPA yii, ki wọn si ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ, iru atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe sara ile ti wọn fẹẹ tun ṣe naa, nitori pe ijiya nla lo wa fẹni to ba lu ofin naa bayii.

Atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko fi sita lọ bayii pe, ‘O ṣe pataki pupọ fawọn eeyan ipinlẹ Eko ti wọn fẹẹ ṣatunṣe sara ile wọn, yala eyi ti wọn n gbe lọwọ tabi eyi ti wọn fi rẹnti fawọn eeyan, wọn kọkọ gbọdọ lọọ gbawe aṣẹ lọdọ ajọ LASPPPA, ki wọn salaye iru atunṣe ti wọn fẹẹ ṣe sara ile naa dori bi wọn ba fẹẹ lẹ taisi silẹ ile wọn. Awọn oṣiṣẹ ajọ naa si gbọdọ waa wo iru ohun eelo tawọn to n ṣiṣẹ naa n lo lasiko ti wọn n kọle naa lọwọ, eyi ṣe pataki pupọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Eko lapapọ.v

Leave a Reply