Ọrẹoluwa Adedeji
Ọmọkunrin to maa n mura bii obinrin, ti iwa ati iṣeṣi rẹ jọ ti obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, ti kuro ni orileede Naijiria bayii o, o ti rinrin-ajo lọ s’Oke-Okun, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i mọ ilu to lọ.
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni ọmọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Mummy of Lagos yii gbe e sori ayelujara pe oun ti rin-irinajo o, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ibi to lọ sibẹ.
Okunnẹyẹ ni, ‘’Ọmọbinrin ti ẹ n wo yii ra tikẹẹti ijokoo akọkọ ninu ẹronpileeni lẹẹmẹta ọtọọtọ, miliọnu lọna ọgbọn Naira lowo ta a n sọrọ rẹ yii o. Ẹ gbe oṣuba fun ọmọbinrin yii jare’’.
Ninu aworan kan to gbe jade lo ti fi ara rẹ han nibi to ti wa ninu baaluu, to si n jaye ọba pẹlu ohun mimu kan to gbe lọwọ, to si n ba awọn kan sọrọ ninu ọkọ ofurufu naa.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu yii ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu nilẹ wa, (EFCC), tu Bobrisky silẹ lahaamọ wọn to wa lẹyin ti wọn wọ ọ bọ silẹ ninu ọkọ baaluu to fẹẹ gbe e lọ si London, ti wọn si ni o ni ẹjọ lati jẹ.
Ohun ti EFCC lawọn tori ẹ mu Bobrisky ni lati waa sọ tẹnu ẹ lori fọnran kan to ti ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa kan gba owo lọwọ oun lati fagi le ẹsun pe o n ṣe agbodegba owo fawọn kan. Wọn ni awọn ti ranṣẹ pe e tipẹ, ṣugbọn ti ko da awọn lohun, eyi lo fa a tawọn fi lọọ fọwọ ofin mu un ni nunu baaluu ni papakọ ofurufu.
Nigba ti Mummy of Lagos de olu ileeṣẹ EFCC niluu Abuja, niṣe lo sọ pe oun ko sọ oun to jọ bẹẹ. Bẹẹ lo ni ohun oun kọ ni wọn gbọ ninu fọran naa, nitori oun ko ba ẹnikẹni sọrọ, bẹẹ loun ko mọ nipa ohun ti wọn ni oun sọ yii. O fi kun un pe bi ẹnikẹni ba ni ẹri lati fi gbe ohun ti wọn sọ yii lẹsẹ, ki wọn mu un jade.
Eyi lo mu ki wọn tu ọmọkunrin naa silẹ. Sugbọn ni bayii, o ti fi orileede Naijiria silẹ, boya London to fẹẹ lọ ki wọn too mu un naa lo pada lọ ni tabi ibomi-in, ni ALAROYE ko ti i le sọ.