Ṣẹyin naa ti gbọ ohun ti awọn obinrin kan ṣe fun Portable olorin

Adewale Adeoye

Ni bayii, ẹgbẹ awọn obinrin to dalemọṣu, iyẹn awọn obinrin ti ko si nile ọkọ ti wọn n pe ara wọn ni ‘Ọmọtọṣọ Single Mothers Association’ (OSMA), ti wọn ni ẹka jake-jado orileede yii ti foye ‘Baba Isalẹ’ ẹgbẹ wọn da gbajumọ akọrin taka-sufee nni, Abeeb Okikiọla, ẹni tawọn eeyan mọ si Portable lọla.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni awọn oloye ẹgbẹ naa fẹnu ko laarin ara wọn, ti si kede pe awọn ti yan Portable gẹgẹ bii baba isalẹ ẹgbẹ naa, ko le maa tọ awọn sọna nigba gbogbo.

ALAROYE gbọ pe awọn dalemọṣu kan ni wọn kora wọn jọ lojuna ati maa ja fẹtọọ wọn labẹ ofin nigba gbogbo. Wọn ni oniruuru idi lo sọ awọn  ọmọ ẹgbe naa di ẹni to n dalemọsu bayii. Wọn ṣalaye pe  awọn ọmọ ẹgbẹ kan wa to jẹ pe wọn kọ ọkọ wọn silẹ ni, ipinya ojiji de saarin awọn kan, awọn kan ko tiẹ lọkọ rara, nigba tawọn kan padanu ọkọ wọn lojiji. Gbogbo irufẹ awọn eeyan yii ni wọn para pọ, bayii ti wọn da ẹgbẹ dalemọsu ọhun silẹ, ti wọn si fi Portable joye baba isalẹ ẹgbẹ naa.

Lara awọn orileede ti ẹgbẹ naa ni ẹka si ni ilẹ Gẹẹsi, Australia, Dubai, Libya, Cairo ati ilẹ Amẹrika.

Portable paapaa ti fi idunu rẹ han si oye pataki ti wọn fi da a lọla yii, nitori pe loju-ẹsẹ lo ti gbe iroyin ayọ naa sori ẹrọ ayelujara rẹ lati fidi oye tuntun to ṣẹṣẹ jẹ ọhun ọhun mulẹ fawọn ololufe rẹ gbogbo.

Ninu fidio to gbe sori  ayelujara ni ọmọkunrin olorin to ti rinrin-ajo lọ si orileede Amẹrika ba a ti n sọ yii ti wọ aṣọ ẹlẹgbẹ-jọ-da kan pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ, to si n rẹrin-in nigba to wa laarin wọn.

Pẹlu oye baba isalẹ ti wọn fi da Portable  lọla yii, oye rẹ ti lekan si i, nitori oun yii kan naa ni wọn n pe ni ‘Ika Of Africa, Amuludun, Federal Government Liability, Tony Montana of London, Police Ambassador ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply