Jọkẹ Amọri
Ki i ṣe tuntun mọ pe Priscilla, ọmọ Iyabọ Ojo, oṣere ilẹ wa to bẹ daadaa nni, ti mu ọmọkunrin kan, Juma Jax, wale lati orileede Tanzania, to ni oun loun fẹẹ fi ṣe ade ori, ti ipalẹmọ si ti n lọ ni rẹbutu lori bi ọjọ naa yoo ṣe dun, ti yoo larinrin, lọdun to n bọ ti wọn fi igbeyawo ọhun si.
Ṣugbọn ni bayii, oṣere ilẹ wa ti wọn maa n pe ni Iya Ire, iyẹn Toyin Abraham, ti jade sọrọ nipa ọmọ Iyabo Ojo ati ohun to maa ṣẹlẹ nipa ayẹyẹ igbeyawo ọhun.
Laipẹ yii ni Iyabo Ojo ati ọmọ rẹ, Prisiclla, gbe foto kan to rẹwa daadaa ti wọn jọ ya, nibi ti wọn ti jọ wọ aṣọ funfun, ti wọn si tun wọ aṣọ ofi kan naa jade.
Gbogbo awọn to ri fọto naa ni wọn n ki wọn, ti wọn si n yin Iyabọ fun itọju to ṣe fun ọmọ rẹ to rẹwa daadaa yii titi to fi di ẹni obinrin, to si to ile ọkọọ lọ.Ọpọ awọn oṣere bii Iyabọ ni wọn ti fi idunnu wọn han si fọto naa, ti oniukaluku si n kọ awọn ọrọ daadaa sabẹ fọto ọhun.
Fọto naa ni Toyin Abraham ti ọkọ rẹ naa jẹ oṣere ti wọn maa n pe ni Iya Ire ri toun naa fi kọ ọrọ nipa rẹ. Ṣugbọn ohun ti oun kọ yatọ patapata si ohun ti awọn ẹgbẹ rẹ yooku kọ, nitori ajọṣepọ to wa laarin Toyin ati ọmọ Iyabọ Ojo.
Toyin kọ ọ pe, ‘’Jesu oo, ẹ wo o, Aunti Iyabọ, lọjọ yẹn, temi paapaa maa ju tiyin lọ..’’
Bẹẹ ni Iyabọ Ojo naa da a lohun pe, ‘wọn ko mọ pe iwọ gan-an ni ojulowo iya iyawo ti a n palẹ rẹ mọ ni…’’
Bẹẹ ni Toyin naa tun da Iyabọ lohun pe, ‘’Wọn ko mọ ni, iba jẹ pe wọn mọ ni, ẹ wo o, ara n ha mi, ara mi ti wa lọna fun ti ayẹyẹ igbeyawo naa’’.
Ọpọ eeyan ni ko mọ pe Priscilla ati Toyin sun mọ ara wọn gidigidi, bii iya at’ọmọ ni wọn jọ maa n ṣe. Oṣere naa fẹran ọmọ Iyabọ yii de gongo, bẹẹ ni Priscilla naa si fẹran Toyin, bii iya lo ṣe mu un.
Tẹ o ba gbagbe, asiko kan wa ti Priscilla ṣẹ ayẹyẹ ọjọobi rẹ, ti Toyin Abraham si wa nibẹ to nawo fun un daadaa, ti wọn si n so mọra wọn kiri.
Ọdun to n bọ ni wọn fi ayẹyẹ igbeyawo ti wọn ti n pariwo pe o maa lẹtikẹ yii si, ṣugbọn ko ti i sẹni to mọ ọjọ ati oṣu to maa jẹ gan-an, nitori awọn mọlẹbi iyawo to n bọ lọna naa ko ti i kede rẹ.