Ọrẹoluwa Adedeji
Ariwo ayọ nla lo tun sọ laafin Adimula Ileefẹ, Ọba Adeyẹyẹ Ẹnitan Ogunwusi, pẹlu bi ọkan ninu awọn olori Kabiyesi, Olori Ashely Fọlaṣade Ogunwusi, ṣẹ bimọ ọkunrin lantilanti bayii. Yatọ si pe o jẹ aya ọba, ọmọọba ni Olori yii, nitori ile ọba Ile-Idf ni Olori Fọlaṣade ti wa.
Funra Kabiyesi lo kede ayọ abara tintin yii lori opo ayelujara rẹ laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan yii, nibi to ti gbe fọto ara rẹ ati ti Olori Fọlaṣade si i, to si kọ ọ sibẹ pe, ‘’Ogo ni fun Ọlọrun fun ohun nla to ṣe fun wa. ‘’Mo ki gbogbo ile Oodua lapapọ ati Olori Fọlaṣade, ẹni to bi ọmọọba lati idile iya rẹ, ti i ṣe Ọọni Adagba, ti idile Lafogídò, ati ti idile baba rẹ to jẹ Oọni Agbẹdẹgbẹdẹ, ti dile Giesi lapapọ, si itẹ Oduduwa.
Iya ati ọmọ wa lalafaia, wọn n ṣe daadaa si ogo Ọlọrun, ati ni ilana ẹmi awọn baba nla wa. O ti ṣee ṣe.
Tẹ o ba gbagbe, loṣu to kọja yii ni wọn ko awọn ibeji ti Olori Tobi, ọkan ninu awọn Ayaba laafin Ọọni Ifẹ to bi ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, wọ aafin wa, ti Kabiyesi si foju kan wọn fun igba akọkọ.
Ni bayii, ayọ abara tin-in-tin mi-in ti tun wọ Aafin ile-Ifẹ.