Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ s’awọn ọmọ Naijiria ni UK

Monisọla Saka

Inu idaamu ati iporuru ọkan lawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan ti wọn n kawe nileewe giga lorilẹ-ede UK, Teesside University, wa bayii, pẹlu bi wọn ṣe ni ki wọn pa ẹru wọn lẹnu pọ, ki wọn pada sibi ti wọn ti n bọ, nitori owo ileewe ti wọn ko ri san.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin BBC, ti pupọ wọn ba sọrọ ṣe sọ, agbẹnusọ Fasiti ọhun sọ pe owo ti wọn ko ri san yii yoo lapa buruku lori fisa wọn, nitori ọwọ ileewe ọhun ni ọrọ igbeluu awọn akẹkọọ yii wa.

Lasiko ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ wiwọle ati ijade awọn eeyan, to fi mọ iwe igbeluu wọn lorilẹ-ede UK (Home Office), n juwe ile fun wọn lẹyin ti awọn alaṣẹ ileewe naa fẹjọ wọn sun, ni wọn sọ fun wọn pe ko si ipẹ kankan tabi ẹbẹ yoowu ti wọn fẹẹ bẹ nitori ọrọ iwe kika ni nnkan to gbe wọn wọ UK.

Owo Naira, ti wọn lo ja walẹ lo ba owo ti wọn ni nipamọ jẹ, ti ọpọlọpọ wọn si n sọ pe ẹka ileeṣẹ to n gba gbese ti kan si awọn.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn akẹkọọ bii ọgọta fẹhonu han pẹlu paali pelebe pelebe ti wọn kọ ẹdun ọkan wọn loriṣiriṣii si ninu ọgba ile-ẹkọ naa.

Bakan naa ni wọn tun naka aleebu si ileewe naa pe ọdaju ni wọn.

Owo Naira ti wọn ni o fọ lojiji, lo ṣakoba fun owo ti wọn ni nipamọ, ti atirowo ileewe san fi di ọran si wọn lọrun, nitori ki wọn too bẹrẹ eto ẹkọ wọn yii ni ileewe ọhun ti ni ki wọn mu iwe ti yoo fidi rẹ mulẹ pe wọn ni owo to to owo lati kawe, ati lati gbe aye irọrun niluu oniluu ti wọn ti fẹẹ waa kawe.

Awọn akẹkọọ yii ni awọn tun gbiyanju lati jokoo sọrọ lori ọna lati ṣeto bi awọn ṣe fẹẹ sanwo naa pẹlu awọn alaṣẹ ileewe, lẹyin ti gbogbo owo ti wọn tọju pamọ ti poora, amọ ti wọn ko gba.

Ọkan ninu awọn akẹkọọ tọrọ yii kan, Adenikẹ Ibrahim, toun pẹlu ọmọ ẹ ọkunrin jọ wa ni UK, ti wọn paṣẹ pe kawọn mejeeji palẹ ẹru wọn mọ, ṣalaye pe pẹlu bi oun ṣe sanwo oun tan, wọn ko jẹ k’oun tẹsiwaju ninu ẹkọ oun. Dipo eyi, niṣe ni wọn ni k’oun ati ọmọ oun maa wa lọ.

Iwọnba akoko perete ni wọn ni o ku fun obinrin yii lati pari eto ẹkọ ọlọdun meji to n ṣe nileewe naa, amọ nitori ti ko ribi san owo kan, wọn da eto ẹkọ rẹ duro, wọn si lọọ fẹjọ rẹ sun ni Home office.

Home office yii ni wọn ti pa a laṣẹ f’oun atọmọ ẹ lati kuro ni UK ni kiakia.

O ni, “Mi o tete sanwo mi pe, amọ mo ti san ida aadọrun-un ninu ọgọrun-un owo naa, ti mo si n lọ si gbogbo kilaasi mi.

Mo pe wọn lati pe ka jokoo sọrọ lori owo yii, amọ wọn ko dahun, nitori ọrọ awọn akẹkọọ wọn ko jẹ wọn logun. Wọn ko fẹẹ mọ ohun to ba ṣẹlẹ si awọn akẹkọọ wọn.

Ibanujẹ nla ni ọrọ yii jẹ fun ọmọ mi, inu idaamu loun naa wa latigba ti mo ti sọ fun un”.

Obinrin yii ni lẹyin t’oun san owo toun jẹ silẹ tan, wọn ko tori ẹ jẹ ki oun lanfaani si eto ẹkọ toun n ba lọ nibẹ k’oun le pari ẹ.

Esther Obigwe, t’oun naa jẹ ọkan lara awọn ti wọn fọwọ osi juwee ile fun sọ pe oogun to n mu adinku ba ijamba ti ironu n ṣe fun agọ ara loun n ko jẹ bayii latigba ti wọn ti jẹ ki oun pa ẹkọ oun ti ni tipa. O ni gbogbo ọna loun ti wa lati ba ileewe naa sọrọ lori adojukọ oun lori owo sisan, ṣugbọn ti wọn ko foun lesi, afi bi wọn ṣe ti itakun agbaye ikẹkọọ oun lori ayelujara ileewe naa pa, pe oun ko le kawe nibẹ mọ, ati pe k’oun kuro lorilẹ-ede naa ni kiakia.

“Mi o ki i pa kilaasi ati sẹmina jẹ, akẹkọọ to duroore ti ki i fi ohun yoowu to ba ni i ṣe pẹlu ẹkọ ṣere ni mi. O ba ni lọkan jẹ pe oogun ti ko ni i jẹ ki ironu pa mi lara ni mo n lo bayii. Pẹlu bi mo si ṣe da wa nibi, mi o rẹni ba sọrọ, ko si alafọrọlọ kankan.

Lati bii oṣu meji bayii, mi o fi bẹẹ sun tabi jẹun da bii alara. Emi o si mọ idi ti wọn fi n ṣe bayii fun wa, a ko huwa aidaa kankan”.

Wọn ṣalaye siwaju si i pe ọrọ fifun akẹkọọ ni fisa tabi gbigba a pada wa lọwọ ileewe. Nitori ti wọn ba din iye ọdun to yẹ ki fisa fi wulo ku, tabi ti wọn fagi le e, afi kiru ẹni bẹẹ gbe igbesẹ lori bi yoo ṣe ṣe ọrọ igbeluu rẹ tabi ko tete ṣeto bi yoo ṣe fi UK silẹ.

Ileeṣẹ Home Office naa sọ ninu lẹta ti wọn kọ pe awọn akẹkọọ ko ni ẹtọ kankan lati ṣipẹ pe ki wọn jẹ kawọn duro.

Leave a Reply