Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si Lalaa onitiata

Faith Adebọla

Bi olorin atijọ kan ṣe kọ ọ, ‘iya ni wura, baba ni digi, ọjọ iya ku ni wura bajẹ, ọjọ baba ku ni digi wọ’mi’. Orin yii lo ṣe rẹgi pẹlu ẹdun ọkan to ṣẹlẹ si ọkan ninu awọn irawọ oṣere ilẹ wa, to tun ti di olokoowo burẹdi bayii, Ọgbẹni Muyideen Ọladapọ, tawọn eeyan mọ si Lalaa, latari bo ṣe padanu mama rẹ.

Funra ọkunrin ọhun lo tufọ iku mama rẹ laṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ta a wa yii.

Ninu fidio kan ti Lala gbe soju opo ayelujara rẹ ọhun lo ti ṣafihan ibi ti oun ati mama naa ti jọ di mọra wọn gbagi nigba to lọọ ki i. Bo ṣe n fọwọ gbe wọn lẹẹkẹ jo, bẹẹ lo tun ilẹkẹ ọrun wọn ṣe, ti mama ọhun n jo pẹlu idunnu bo ṣe foju kan ọmọ rẹ, toun ati-ẹ si jọ n dọwẹkẹ, ti wọn n ṣere iya sọmọ. Labẹ fidio ọhun ni Lalaa ti kọ ọrọ ṣoki pe: Mi o mọ nnkan ti mo le sọ, o ti sa pa mi lori! Ko si okun ninu mi mọ. Alaaja! Ẹ dẹ lọ bẹẹ yẹn ṣa?

Awọn ti wọn sun mọ oṣere naa, ti wọn si ti gbọ nipa ọfọ nla to ṣẹ ẹ ni wọn tete loye fidio to gbe si i ọhun, ibẹ ni ojo ikini ati ibanikẹdun ti bẹrẹ si i rọ, bawọn ololufẹ rẹ ṣe n tu un ninu, ti wọn n ni ko mọkan le, bẹẹ lawọn oṣere tiata ẹlẹgbẹ rẹ naa n ṣe.

Oloye Fẹmi Branch ni: Pẹlẹ o, Arakunrin. Ibi to daa ju ni mama wa kọja si, mo si mọ pe inu rẹ yoo maa dun si ọ bo o ṣe n ṣe rere.

Mirabellesexy28 sọ pe: O maa n dun-unyan wọnu egungun, amọ niṣe ni kẹ ẹ mọkan le o, Ẹgbọn. Ọjọ aa jinna sira wọn.

Ninalowo ni: O ṣoro lati gbagbọ. A fẹ ọ, ṣugbọn Ọlọrun fẹ ọ ju.

Akin Ọlaiya, Adeniyi Johnson, Kelvin Ikeduba, Madam Ṣajẹ ati ọgọọrọ oṣere bẹẹ ni wọn daro iya Muyideen Ọladapọ, ti wọn si ṣadura fun un.

Bẹẹ lawọn mi-in si gba Lalaa lamọran lati tufọ iku mama rẹ ni taarata, dipo ti yoo fi jẹ kawọn ololufẹ rẹ ṣẹṣẹ maa beere pe ki lo ṣẹlẹ si i.

Leave a Reply