Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si Small Doctor olorin

Adewale Adeoye

Titi di akoko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ, ko sẹni to le sọ ni pato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba ina kan to deede ṣẹ yọ ninu ile gbajumọ olorin hipọọpu nni, Ọgbẹni Adekunle Temitọpẹ, ẹni tawọn ololufẹ rẹ mọ si Small Doctor. Lojiji ni ina buruku ọhun deede ṣẹ yọ ninu ile omọkunrin olorin naa, kawọn eeyan to wa nitosi ile ọhun si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ina ọhun ti fẹju gidi to bẹẹ tawọn ara agbegbe naa fi n sa kijo-kijo lati bomi pa a, ṣugbọn ti apa wọn ko ka a, afigba tawọn kan sare pe awọn osiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinle Eko wa pe ki wọn waa ba Small Doctor pana to n jo ile rẹ yii.

O le ni wakati kan tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti wọn pe too lanfaani lati pana ọhun, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe aimọye dukia olowo iyebiye to jẹ ti gbajumọ olorin ọhun ni ina ọhun ti jo deeru patapata.

Afi bii igba ti wọn ran ina ọhun sile Small Doctor ni, nitori  ṣe lo n fẹju si i pẹlu bi wọn ṣe n bomi pa a to.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ijamba ina ọhun ṣẹlẹ si Small Doctor, dukia olowo iyebiye lo si ba ijamba ọhun lọ. Ọpọ awọn ololufẹ olorin naa ni wọn ti n ba a daro, ti wọn si n ṣadura fun un pe Ọlọrun yoo fi ọpọlọpọ rọpo ohun gbogbo ti ina ti jo nile rẹ.

Ṣa o, ọmọkunrin olorin naa ti sọrọ lori iṣẹlẹ ijamba ina ọhun, eyi to jo gbogbo dukia ile rẹ bajẹ. O ni, ‘Ẹ ba mi dupẹ ẹyin ololufẹ mi gbogbo pe ile ati dukia mi lo jona, ẹmi mi tabi tawọn ololufẹ mi ko jona mọ’nu ile ọhun, ko si wahala kankan, ile ọba to jona, ẹwa lo bu kun un. Iyaanu ṣi maa ṣẹlẹ laipẹ yii, mi o fọ rara, koda, mi o mikan lori ohun to ṣẹlẹ si mi yii’.

Leave a Reply