Ṣẹyin naa ti gbọ ohun to ṣẹlẹ si Sunday Igboho

Faith Adebọla

Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Kejila yii, ni ile-ẹjọ kan ti wọn pe ni Community Court of Justice of the Economic Community of West African States, (ECOWAS), paṣẹ niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa pe ki orileede Benin san miliọnu lọna ogun (20 million CFA), to jẹ owo orileede naa, eyi ti o n lọọ bii miliọnu mẹrindinlọgbọn owo ilẹ wa (26, 456, 969.43m) fun ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Igboho, lori bi wọn ṣe fi ẹtọ rẹ ẹ du u, ti wọn si tun ti i mọle lọna ti ko bofin mu fun ọpọlọpọ oṣu ni orileede naa.

Ninu idajọ ti gbogbo awọn adajọ ọhun, eyi ti Onidaajọ Gberi-Bé Ouattara; Sengu M. Koroma and Ricardo Claúdio

Monteiro GONÇALVES, fẹnu ko si, ninu ẹjọ ti nọmba rẹ jẹ

ECW/CCJ/APP/15/22, eyi to wa laarin Oloye Sunday Adeyẹmọ (aka Sunday Igboho), pẹlu Republic of Benin, ni ile-ẹjọ ọhun ti paṣẹ pe ki orileede naa san owo naa, ki wọn si tẹle aṣẹ ile-ẹjọ nipa ṣiṣe bẹẹ laarin oṣu mẹta, ki wọn si waa fi abọ jẹ ile-ẹjọ nipa mimu ẹri risiiti ti wọn fi san owo naa wa sile-ẹjọ.

Awọn agbẹjọro to ṣoju Igboho nibi igbẹjọ naa ni Tosing Ọlajọmọ, Aderẹmilẹkun Ọmọjọla Esq; Dr Janet Fashakin Esq, nigba ti Irene Aclombessi, ṣoju fun orileede Benin.

Nigba to n ba ALAROYE lori idajọ naa lati orileede Germany ti ajijagbara ọmọ Yoruba yii wa lo ti sọ pe idunnu nla ni idajọ ile-ẹjọ naa jẹ foun.

Sunday Adeyẹmọ ti wọn tun maa n pe ni Igboho Ooṣa ni: ‘‘Inu mi dun gidigidi fun idajọ naa, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da mi lare. Ohun to mu inu mi dun ju ni pe awọn orileede alagbara meji ni mo koju, ta ni mi laarin awon alagbara Naijiria ati Benin, ṣugbọn mo dupẹ pe Ọlọrun da mi lare, o wọnu awọn adajọ naa, gbogbo wọn si da ẹjọ naa si ibi kan naa.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun’’.

Nigba ti akọroyin ALAROYE beere boya wọn ni idaniloju pe wọn maa ri owo ti wọn ni ki wọn san fun wọn yii pada, Igboho ni, ‘‘ALAROYE, ẹ jẹ ka tilẹ gbe ọrọ owo yii ti sẹgbẹẹ kan na, ohun to dun mọ mi ninu ju ni pe Ọlọrun da mi lare, o si foju han gbangba pe lọna aitọ ni wọn fi ti mi mọle, ti mo si waa di ẹni idalare bayii. Eyi dun mọ mi ninu ju ohun gbogbo lọ’’.

Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti Igboho n lọ si orileede Germany ni wọn da a duro lorileede Benin, ti wọn si gbe e lọ sile-ẹjọ, latibẹ ni wọn ti gbe e lọ si kootu, ti wọn si ti i mọle fun ọpọlọpọ oṣu ko too di pe wọn tu u silẹ laipẹ yii.

Ki i ṣe orileede Benin nikan ni Igboho gbe lọ si kootu, bakan naa lo ti gba idalare nile-ẹjọ kan niluu Ibadan, lori bi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa ṣe ya wọ ile rẹ, ti wọn si paayan nibẹ.

Leave a Reply