Monisọla Saka
Ọkunrin agbofinro kan, Ahmed Ali, ti ṣe bẹẹ ki aye pe o digbooṣe lẹyin tawọn ṣọja kan niluu Benisheikh, nipinlẹ Borno, yinbọn fun un, nitori pe oun atawọn ikọ rẹ da ṣọja kan duro lasiko to n fi mọto ko igbo lọ.
Awọn ẹṣọ alaabo agbegbe naa ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye lẹnu odi ilu ọhun, nibi ti wọn ti maa n da awọn eeyan ati ọkọ duro lati yẹ awọn ohun ti wọn ba ko wo, ti wọn yoo si fọwọ ofin mu awọn to ba ko ẹru to lodi sofin.
Ọkan ninu awọn ẹṣọ alaabo agbegbe ibẹ ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe ọkunrin ṣọja ọhun to wa ọkọ Acura sport, alawọ eeru kan ti nọmba rẹ jẹ FKJ 761 AR, kọ lati duro ni abawọle ilu ọhun nigba tawọn ọlọpaa da a duro.
“Ohun to mu un ti ko fi duro yii lo jẹ ki ikọ awọn agbofinro Keystone, yii yinbọn si taya ọkọ rẹ, eyi si mu ki ọkọ naa duro sii lojiji. Ṣọja to fi ọkọ gbe igbo ọhun, Sajẹnti U. Joseph, pẹlu awọn yooku rẹ, gbiyanju lati da awọn ikọ ọlọpaa naa duro pe ki wọn ma mu mọto awọn, ki wọn ma si gbe e de agọ wọn. Lasiko ti Sajẹnti Ali n gbiyanju lati wa ọkọ naa lọ si teṣan ọlọpaa Benisheikh, lawọn ṣọja yinbọn pa a”.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Leadership ṣe sọ, afurasi naa wa lakata awọn ileeṣẹ ologun bayii, nigba ti ọkọ ti wọn fi ko igbo wa ninu teṣan ọlọpaa Benisheikh.
Ọkan ninu awọn ṣọja ọhun ṣalaye pe ki i ṣe pe awọn fẹẹ pa ọkunrin ọlọpaa ọhun, o ni aṣiṣe ni ibọn to ba a to fi ku ọhun, O ni Ibrahim Waberi, to ṣi ibọn ọhun ta kan fẹẹ yinbọn si mọto naa ki wọn ma baa gbe e lọ ni, to fi waa jẹ pe oloogbe lo lọọ ba.
O fi kun un pe ṣọja ti wọn fẹsun kan ọhun ti wa nibi to ti n kawọ pọnyin rojọ, bẹẹ ni iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.