Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ to kọja, ni Abdulganiyu Barakat Motunrayọ, ẹni ọdun mẹtadinlogun, to n lọ sileewe girama Cherubim ati Seraphim, niluu Ilọrin, to si wa nipele keji SS2, to tun n kọṣẹ baagi ṣiṣe di awati lagbegbe Yoruba road, Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti gbogbo akitiyan awọn mọlẹbi lati sawari ẹ si ja si pabo.
Iroyin to tẹ ALAROYE, lọwọ ni pe, Motunrayọ n gbe pẹlu anti rẹ ni, o si jade nile lowurọ kutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ yii, ti ko si dari wọle mọ.
Wọn ni ẹni ọdun mẹtadinlogun ni Motunrayọ, o ga niwọn ẹsẹ bata marun-un, o pupa fẹẹrẹfẹ. Wọn ti waa rọ gbogbo ẹni to ba kẹẹfin ọmọbinrin yii nibikibi, ki wọn mu un lọ si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn ju lọ, tabi ki iru ẹni bẹẹ pe awọn mọlẹbi si awọn Nọmba ibanisọrọ yii: 08038987149, 07067961849.