Jamiu Abayọmi
Ọkunrin ajafẹtọọ-ọmọniyan to tun jẹ oludije funpo aarẹ orileede yii ninu idibo aarẹ to kọja loṣu Keji, ọdun yii, labẹ asia ẹgbẹ African Action Congress (AAC), Ọmọlẹyẹ Ṣoworẹ, ti ni ikoriira nla ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ẹbunoluwa Adelesi, ni fun ọmọkunrin oniṣẹṣe to wa latimọle nni, Adegbọla Abdulazeez, ti gbogbo eeyan mọ si Ta-ni-Ọlọrun. O fi kun un pe fọnran gbogbo awọn ohun ti ọga ọlọpaa naa sọ nibi to ti n sọrọ ikorira lori ọkunrin naa wa lọwọ oun bii ẹri.
Áoworẹ ṣalaye ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn oniroyin kan l’Ọjọruu Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, nibi to ti ni gbogbo ọrọ ti kọmiṣanna naa sọ lori foonu nipa Ta-ni-Ọlọrun lo wa lọwọ oun, paapaa lori ẹsun to n jẹjọ lori rẹ lọwọ ni kootu pe o n bu awọn aafaa Ilọrin.
“Emi gbagbọ ninu pe ọfẹ loun, ohun to wuuyan lo le fi ẹnu rẹ sọ, bẹẹ tun ni pe ẹsin to ba wu ẹnikeni lo le ṣe, lati ibẹrẹ ọrọ Ta-ni-Ọlọrun ni mo ti n ba wọn bọ, ti mo si gbagbọ pe wọn lọọ ji ọmọkunrin oniṣẹṣe naa gbe ni ti wọn fi gbe e lọ si kootu awuruju kan.
“Kọmiṣanna ọlọpaa yẹn lẹdi apo pọ mọ awọn ti ko fẹ ti Ta-ni-Ọlọrun ati awọn ti ko fẹ kawọn oniṣẹṣe sin ẹsin wọn nipinlẹ Kwara ni, oun ti wọn ṣe yẹn ko daa rara, wọn o si lẹtọọ lati pe e lẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an naa. Ohun ti eyi si n ṣafihan ni pe ọga ọlọpaa yẹn gan-an ko fẹẹ gbọ orukọ Ta-ni-Ọlọrun seti ni.
“Ko tiẹ yẹ ki wọn wọ ọ lọ sile-ẹjọ Majisireti kankan debii pe adajọ tun wa n sun igbẹjọ si aadọta ọjọ miiran lori ẹsun ti ko ju ki wọn gba beeli rẹ lọ, iyẹn to ba tiẹ ṣẹ rara. Ṣugbọn ko tiẹ waa ṣe nnkan kan to ta ko ofin rara bayii.
‘‘Ta-ni-Ọlọrun kan n gbiyanju lati sọ ero tiẹ lori ọrọ ẹsin Iṣẹṣe ẹ ni, to ba jẹ pe awọn nnkan to sọ sibẹ ko ba daa ni, oju opo Facebook to fi si yoo ti le e danu pe o ru ofin wọn.
“Awọn Aafa yẹn kan lo ajọṣepọ ti wọn ni pẹlu kọmiṣanna to ti sọrọ ikorira nipa ọmọkunrin naa lori foonu tẹlẹ, ti mo si ni lọwọ bayii lati fọwọ ọla gba a loju ni. Wọn gbimọ ọtẹ pọ lati ji ọkunrin naa gbe re kọja si ipinlẹ mi-in pẹlu iwe ẹsun arumọjẹ lati ile-ẹjọ giga kan.
“Ile-ẹjọ giga kan ko laṣẹ nipinlẹ mi-in. Loootọ, mi o ki i ṣe lọọya, ṣugbọn mo mọ nipa awọn nnkan yii nitori mi o jinna sile-ẹjọ, gbogbo igba nijọba maa n pe mi lẹjọ. Mo ti pe fun iyọkuro kọmiṣanna naa, ko yẹ lẹni ti wọn yoo maa pe lọlọpaa, pẹlu bo ṣe lọwọ si bi wọn ṣe lọji Ta-ni-Ọlọrun gbe lati ipinlẹ Ọyọ lọ si Kwara pẹlu iwe ẹsun arumọjẹ’’.
Ṣoworẹ ni fọnran fidio kan naa tun wa, nibi tọkunrin kan ti n sọ pe oun tan Ta-ni-Ọlọrun debi tawọn ọlọpaa Kwara ti gbe e ni. O ni niṣe lo yẹ ki wọn lọ si ipinlẹ Ọyọ lati lọọ pe e lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ nile-ẹjọ giga tipinlẹ naa, yatọ fun bi wọn ṣe ji i gbe lọ si Kwara. O ni bi ẹjọ naa ṣe n lọ, ko si bi ọmọkunrin yẹn ṣe fẹẹ ri idajọ ododo gba bi iru awọn yii ko ba dide lati ja fun un.
“Iru nnkan ti wọn n ṣe yii ni awọn ijọba ti wọn ko wa lẹru n lo nigba naa, ile-ẹjọ si ti dawọ rẹ duro lati ọdun 1983. Onidaajọ Babatunde Belgore to jẹ ọmọ ipinlẹ Kwara wọn yii kan naa wa lara awọn igbimọ to da ofin naa duro lọdun naa lọhun”.
O kadii ọrọ rẹ pe ọwọ ọla ti wọn fẹẹ fi gba ọmọkunrin oniṣẹṣe Ta-ni-Ọlọrun naa loju loun fi duro ti i gbagbaagba ati gbogbo ẹni ti wọn ba fiya jẹ lọna aitọ lorileede yii.