Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Micheal Salakọ lorukọ ọkunrin to sọrikọ yii, awọn to mọ ọn l’Abẹokuta sọ pe o fẹran ko maa ni kawọn ọlọkada gbe oun lai ni i fun wọn lowo. Ọlọkada kan to kọ lati gbe e lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to kọja yii, jiya lọwọ ẹ, afigba tiyẹn ku mọ ọn lọwọ nibi to ti n lu u, ohun to gbe Micheal de ahamọ ọlọpaa niyẹn.
Ṣaaju ki DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ yii lede lọjọ Sannde ọsẹ yii ni awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ti ṣalaye f’ALAROYE, pe Opopona Sanni, ni Lafẹnwa, Abẹokuta, niṣẹlẹ yii ti waye.
Wọn ni ọlọkada naa ti wọn pe orukọ ẹ ni Abudu gbe ẹnikan wa saduugbo naa ni, o si n duro de ẹni naa ko le gbe e pada nitori iyẹn ti sọ fun un pe yoo tun gbe oun pada boun ba ra oogun toun fẹẹ ra tan nile itaja oogun kan.
Nibi to ti n duro de e ni Micheal ti de to ni ko waa gbe oun lọ sibi toun n lọ, ọlọkada naa si sọ fun un pe oun n duro de ẹni toun gbe wa ni.
Eyi ko dun mọ Micheal, wọn ni o ṣaa n kigbe mọ Abudu pe afi ko gbe oun bi ko ba fẹ wahala, ko si pẹ sigba naa lo bẹrẹ si i lu u, bo ṣe ti i lulẹ tiyẹn fori gba okuta niyẹn, o si ṣe bẹẹ dagbere faye.
Awọn eeyan to wa nitosi ni ko jẹ ki Micheal sa lọ, ti wọn pe ọlọpaa to fi dohun ti wọn fa a le wọn lọwọ ni teṣan ọlọpaa Lafẹnwa.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ fun wọn nibẹ, afurasi yii sọ pe loootọ loun ni ki Abudu gbe oun, o si kọ, oun si binu si i, lawọn ba jọ n ja. O ni nibi tawọn ti n ja naa lo ti ṣubu lulẹ to si ku.
Ṣa, wọn ti ni wọn yoo ṣayẹwo si oku ọlọkada naa, wọn si ti gbe e lọ sile igbokuu-pamọ, bẹẹ ni wọn ti taari Micheal sẹka awọn to n jẹjọ ẹsun ipaniyan.