Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ogbologboo oniṣowo igbo kan, Fẹmi Fadeyi, ti wa lakata awọn ọlọpaa niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n sọ ohun to mọ nipa awọn oogun oloro ti wọn ka mọ ọn lọwọ.
Ọkunrin ẹni aadọta ọdun naa lọwọ awọn ọlọpaa RRS tẹ ni adugbo Atikankan, niluu Ado-Ekiti, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ti wọn si gba bii ogoji iwọn igbo ti wọn di sinu iwe pelebe-pelebe ati ẹgbẹlẹgbẹ awọn egboogi miiran bii kolorado ati iyẹfun kokeeni lọwọ rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ni deede aago mọkanla aabọ ọsan ọjọ Abamẹta ni ẹnikan pe awọn pe kawọn maa bọ ni adugbo Atikankan, pe awọn adigunjale kan wa nibẹ.
Bi awọn ọdaran yii ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn ti gbe ere da si i, ṣugbọn awọn agbofinro pada gba Fadeyi mu.
Awọn ẹru ti wọn gba lọwọ Fadeyi ni igbo ti wọn ti pọn sinu iwe pelebe-pelebe to to bii iwọn ogoji, kokeeni to to bii iwọn mẹtalelogoji, ada nla nla oloju meji, ẹgbẹrun lọna mejilelaadota naira.
Awọ agbofinro ni nigba ti awọn fọrọ wa ọdaran naa lẹnu wo, o jẹwọ pe owo egboogi oloro loun n ṣe. O ni niṣe ni oun waa ta awọn egboogi oloro ti wọn gba lọwọ oun fun awọn eeyan kan ni adugbo Atikankan, lọjọ naa ni.
Alukoro sọ pe wọn yoo gbe Fadeyi lọ sile-ẹjọ ni kete tiwadii ba ti pari lori ọrọ naa.