Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti buwọ lu ofin ma-fẹran-jẹko nipinlẹ yii, eyi ti awọn aṣofin Ogun fi ṣọwọ si i lọjọ kẹjọ, oṣu keje, ọdun 2021.
Ọjọbọ, ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, lo buwọ lu aba naa, to si di ofin, iyẹn lọfisii rẹ l’Oke-Mosan, lasiko ti wọn n ṣepade eto aabo.
Gomina pe awọn ẹṣọ alaabo gbogbo lati ji giri si ofin yii, bo tilẹ jẹ pe o fi aaye oṣu mẹfa silẹ fawọn darandaran naa lati wa ibi ti wọn yoo ti maa fun awọn maaluu wọn lounjẹ, ti ko si gbọdọ si pe wọn tasẹ agẹrẹ si ilẹ onilẹ laarin ilu, tabi pe wọn n ko maaluu kiri aarin ilu mọ nipinlẹ Ogun.
Ẹ oo ranti pe ninu oṣu kẹjọ ni awọn gomina apa Guusu lorilẹ-ede yii panu pọ pe awọn ko fẹ ki Fulani kankan fẹran jẹko lọna aitọ mọ, wọn si fẹnuko si pe nigba ti yoo ba fi di oṣu kẹsan-an, ofin naa ti gbọdọ fẹsẹ rinlẹ lapa ibi to kan gbogbo.
Kekere kọ ni ikọlu awọn Fulani ati agbẹ to waye nipinlẹ Ogun lọdun yii, paapaa lapa Yewa. Lati fopin si gbogbo iṣoro naa lo fa a ti Gomina Abiọdun fi gbe igbimọ kan dide nigba naa, pe ki wọn ri si wahala ọhun. Ko too waa pada di ofin wayi.