Adewumi Adegoke
Orire nla lo de ba awọn ọmọbinrin meji tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹsan-an si mejila pẹlu bi Gomina ipinilẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ṣe gba lati maa tọju awọn ọmọ naa, ti yoo si maa gbọ gbogbo bukaata to ba jẹ yọ lori ọrọ ileewe wọn.
Lasiko ti gomina n kaari fun iṣẹ ilu lo ri awọn ọmọ wọnyi ti wọn ru ike lori ti wọn n rin lọ, ni gomina ba da dẹrẹba rẹ duro, lo ba bọ silẹ ninu mọto, o si bẹrẹ itakurọsọ pẹlu awọn ọmọ naa.
Sanwoolu beere idi ti awọn ọmọ naa ko fi lọ sileewe, eyi akọkọ ni awọn obi oun ko ri owo ileewe oun san ni. Ekeji ni oun ṣẹṣẹ de siluu Eko lati Kano ni. Wọn ni awọn n lọ lati jiṣẹ fun aọn obi awọn ni.
Ni gomina ba tẹle wọn ti wọn fi ri awọn obi wọn. Nibẹ lo ti ṣeleri pe oun yoo gbọ bukaata to ba jẹ mọ ileewe awọn ọmọ naa ati itọju wọn.
N ni idunnu ba ṣubu layọ fun awọn ọmọbinrin mejeeji yii.