Ọrẹoluwa Adedeji
Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu ati awọn oludije yooku funpo aarẹ orileede yii lati panu pọ ṣatilẹyin fun Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati gbe apoti ibo lorukọ ẹgbẹ APCl ọdun 2023.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita niluu Eko nipasẹ Agbẹnusọ wọn, Ọgbẹni Olugbenga Ọlaoye, lẹyin ipade wọn ni wọn ti bẹ Tinubu lati ni arojinlẹ lori ipa pataki ti Ọṣinbajo yoo ko nipa idagbasoke orileede yii lẹyin idibo ọdun 2023.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, “Ko si ariyanjiyan kankan nibẹ rara, awọn amuyẹ Ọṣinbajo fun un ni anfaani to pọ lati ṣaṣeyọri labẹ ẹgbẹ APC ninu idibo aarẹ to n bọ.
“Nitori naa la ṣe n rọ Aṣiwaju Bọla Tinubu atawọn lookọ-lookọ mi-in lati gbaruku ti erongba Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, nitori ẹgbẹ wa ati orileede yii lapapọ”.
Ẹgbẹ naa fi kun un pe gbogbo erongba ati igbiyanju Ọṣinbajo lati ba awọn eekan ilu kaakiri sọrọ lawọn ti ṣayẹwo rẹ, bẹẹ ni awọn ko le moju kuro lara awọn ipinnu rẹ lati mu idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba orileede Naijiria.
“Ọsinbajo, lasiko yii, duro gẹgẹ bii olumọ afara to nifẹẹ si orileede ti ifẹ yoo ti jọba. Idi niyi ti a fi n ke si awọn oludije yooku lati panu pọ ṣatilẹyin fun Ọṣinbajo lati di aarẹ orileede yii lọdun 2023”
Ẹgbẹ naa tẹsiwaju pe nipasẹ igbesẹ yii, apa Guusu orileede yii yoo wa niṣọkan ṣaaju idibo apapọ ọdun 2023. O ni bi awọn eeyan ṣe n tẹwọ gba Ọṣinbajo lati ọsẹ diẹ sẹyin to ti bẹrẹ ifikunlukun kaakiri fihan pe ẹni ti wọn nifẹẹ ni.