2023: Ibo miliọnu kan lawa obinrin maa fun Tinubu/Shettima l’Ọṣun- Iyawo Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaja Kafayat Oyetọla, ti sọ pe oun atawọn ẹgbẹ ‘Akọni Obinrin’ yoo ri i daju pe oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, jawe olubori ninu ibo apapọ ọdun to n bọ.

Alhaja Oyetọla tun sọ pẹlu idaniloju pe awọn ‘Akọni Obinrin’ ko ni i faaye gba ibo adiju (Overvoting) lasiko ibo oḍun 2023 gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lasiko idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to waye kọja.

Awọn obinrin naa, lasiko ti wọn n rin kaakiri ilu Oṣogbo lati jẹ kawọn araalu mọ pataki idi ti wọn fi gbọdọ dibo fun Tinubu/Shettima gbera lati ile ijọba ni Oke-fia, kọja si Alekuwodo, lọ si Old Garage, ti wọn si pari ẹ si Nelson Mandela Freedom Park.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Alhaja Oyetọla sọ pe afojusun kan ṣoṣo ti agbarijọ awọn obinrin naa ni ni lati ri i pe Aṣiwaju Bọla Tinubu ri ibo to to miliọnu kan nipinlẹ Ọṣun lọdun 2023.

O ni, “A ti ri oniruuru ara to ti da lorileede yii ati loke okun, paapaa, lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Eko, ẹni to ko gbogbo eeyan mọra ni, ki i ṣe ẹlẹyamẹya. A mọ pe yoo ṣe ju iṣẹ to ṣe nipinlẹ Eko lọ to ba di aarẹ orileede yii.

“Lati le dena adiju ibo, iru eyi to waye lasiko idibo gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun 2022, a maa mojuto ibo wa lẹyin ti a ba di i tan, ko ni i si aaye fun magomago ninu idibo naa, a maa duro ti ẹrọ idibo BVAS ti ẹnikẹni ko ni i le raaye ṣe eru ibo”

Ninu ọrọ tirẹ, alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, sọ pe akọsilẹ kaadi oludibo fi han pe awọn obinrin ti wọn n dibo pọ ju awọn ọkunrin lọ.

Famọdun ṣalaye pe awọn obinrin ni ipa pataki lati ko ninu ẹni ti yoo jawe olubori ninu idibo. O ni pẹlu bi awọn obinrin naa ṣe tu yaaya jade, o daju pe Tinubu yoo jawe olubori lọdun 2023.

 

 

Leave a Reply