Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal Group (ARG) ti sọ pe ilẹ Yoruba ṣetan lati gba ijọba apapọ lọdun 2023, nitori pe gbogbo nnkan to yẹ ni apa Iwọ-Oorun wa nibi ni, ṣugbọn awọn agbaagba gbọdọ gbe igbesẹ.
Ẹgbẹ naa darukọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, Gomina Kayọde Fayẹmi ati Oloye Bisi Akande gẹgẹ bii awọn to le ṣaaju ọmọ Yoruba lati gba nnkan to tọ si wọn, iyẹn ti wọn ba ṣiṣẹ papọ.
Nibẹrẹ ọsẹ yii ni akọwe ipolongo Afẹnifẹre Renewal Group nipinlẹ Ekiti, Ọmọọba Michael Ogungbemi, kede ọrọ naa lasiko to n ṣalaye awọn igbesẹ tẹgbẹ naa n gbe lati ran Yoruba lọwọ pẹlu bi ibo gbogbogboo orilẹ-ede yii ṣe n sun mọ etile.
Ogungbemi ni o ṣee ṣe ki ipo aarẹ ilẹ yii wa silẹ Yoruba, o si ku sọwọ awọn adari ti wọn wa lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lati gbe ẹni kan kalẹ ti yoo gbe ogo Yoruba ga. O ni Tinubu, Fayẹmi, Akande atawọn agbaagba mi-in niṣẹ nla lati ṣe, awọn eeyan yoo si beere lọwọ wọn ti iran Yoruba ba kuna.
Bakan naa lo ni asiko ti to fun atunto ti gbogbo eeyan ti n pariwo tẹlẹ, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo ọmọ ilẹ yii janfaani apapọ, yatọ si bi apa kan ṣe n gbadun ju awọn to ku.
Ogungbemi ni, ‘‘Ilẹ Yoruba ti ṣetan lati gbajọba, ẹgbẹ wa naa si ti ṣe ilana ti yoo mu eyi rọrun, ẹni to maa mu wa de ilẹ ileri naa nikan la nilo.
‘‘A ko le ṣe eleyii ti iyapa ba wa laarin wa. Tinubu, Fayẹmi, Akande, Oloye Reuben Faṣoranti, Ọgagun-fẹyinti Alani Akinrinade, Ọjọgbọn Banji Akintoye, Sẹnetọ Fẹmi Okurounmu. Sẹnetọ Ayọ Fasanmi, Oloye Afẹ Babalọla atawọn mi-in, gbogbo wọn ni wọn ni ipa ti wọn fẹẹ ko.’’