2023: Tinubu jafafa, o si ni iriri lati gbe orileede yii goke agba – Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ti awọn ọmọ orileede yii ba le dibo fun oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lọdun to n bọ, iyansipo rẹ yoo sọ ireti wọn di ọtun. Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, lo sọrọ yii niluu Oṣogbo, nibi ifilọlẹ awọn igbimọ ipolongo Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu atigbakeji rẹ, Kashim Shettima, iyẹn, Directorate of Grassroots Mobilisation Engagement and Orientation, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, O ni Tinubu ni iriri to pọ, eleyii to nilo lati tun itan orileede yii kọ, ati lati gbe e debi giga, o ni oun nigbagbọ ninu awọn ikọ ipolongo ti oun gbe kalẹ naa lati mu ihinrere nipa Tinubu lọ sọdọ awọn eeyan igberiko.

O ni, “Awa wa nibi gẹgẹ bii ikọ Ọmọluabi lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹni to kunju osunwọn, olotito eniyan ati ẹni to ni iriri lati tun orileede yii ṣe.

“A wa nibi gẹgẹ bii eeyan Guusu Iwọ-Oorun orileede yii lati fi ontẹ lu ẹni ti a ti fi agbara dan wo ri, ti a si jẹrii lati ṣe takuntakun ninu mimu ayipada rere ba eto ọrọ-aje. A ti ṣetan lati duro ti oludije ti yoo mu idagbasoke ti ko lẹgbẹ ba orileede yii”

Oyetọla ke si awọn ọmọ igbimọ naa lati lọ kaakiri ilu, ki wọn lọ kaakiri igberiko, ki wọn lọ lati ojule de ojule lati ba wọn sọ nipa Tinubu. O ni afojusun wọn ni lati ri i pe Tinubu jawe olubori ninu idibo apapọ oṣu Keji, ọdun to n bọ.

Ninu ọrọ tirẹ, alaga ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, sọ pe Tinubu ni agbara, bẹẹ lo si ni ilera pipe lati tukọ orileede yii to ba di aarẹ lọdun to n bọ.

Leave a Reply