Nitori ọmọ rẹ to ku, awọn eeyan ba Ebenezer Obey daro

Faith Adebọla, Eko

 Ibanujẹ dori agba kodo, asiko ibanikẹdun ni agba-ọjẹ onkọrin Juju ilẹ wa nni, Oloye Ebenezer Obey-Fabiyi, wa, latari bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Ọlalekan Obey-Fabiyi, ṣe ku lojiji laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.

Wọn ti sinku oloogbe naa lọjọ Satide, ọgbọnjọ, oṣu Keje, to kọja, lẹni ọdun mejidinlaaadọta.

Titi dasiko yii, ko ti i sẹni to mọ pato ohun to ṣokunfa iku ojiji yii, tori ko si akọsilẹ kan pe oloogbe naa ni iṣoro ailera kan, bo tilẹ jẹ pe iku o dọjọ, arun o doṣu.

Ninu fidio kan ti gbajugbaja oniroyin Ovation, Baṣọrun Dele Mọmọdu, gbe sori atẹ ayelujara Instagiraamu rẹ, o ṣafihan Ebenezer Obey niluu London, lorileede United Kingdom, bi pasitọ kan ṣe n gba a lalejo sile rẹ.

Ọpọ awọn ololufẹ baba naa ni wọn ti n ba a daro, ti wọn si n kẹdun pẹlu rẹ, bẹẹ ni wọn n ṣadura pe Ọlọrun yoo dawọ ibi duro nile Ebenezer Obey.

Leave a Reply