Faith Adebọla, Eko
Ọwọ palabi ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji kan to porukọ ara ẹ ni Abass, ti segi o. Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, lọwọ tẹ ẹ lagbegbe Ojodu, nibudokọ Grammar School, pẹlu lailọọnu baagi dudu kan to gbe dani, ẹran eeyan lo ge lekiri-lekiri sinu apo naa, pẹlu ifun, eyin atawọn ẹya ara mi-in, lo ba ko ewe le e lori, o lẹnikan fi i ran oun niṣẹ ni, Oloye Ọbadara lo porukọ ẹni to bẹ ẹ lọwẹ naa.
Ṣe bina ba n jo loko, majala ni i ṣofofo, oorun buruku to gbalẹ lo mu kawọn ero inu ọkọ Maruwa tọkunrin naa wọ lati Berger lọ s’Ojodu lalẹ ọjọ naa fura si ẹru ọwọ ẹ.
Nigba ti ALAROYE ṣabẹwo sagbegbe tiṣẹlẹ naa ti waye laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide yii, a ri onikẹkẹ Maruwa to gbe afurasi naa lalẹ Furaidee, o si ṣalaye b’iṣẹlẹ naa ṣe waye. Baba ti ko fẹ ka darukọ oun naa ni:
“Ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ni mi, emi ni mo ni kẹkẹ Marwa yii, ti mo gbe e fẹnikan pe ko maa fi i ṣiṣẹ. Gbogbo alaalẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an ni mo maa n lọọ gbe e wale. Lalẹ ana, ọjọ Furaidee, bi mo ṣe n bọ, mo ro pe ki n ma kan ṣanwọ ofo wale, ni mo ba gbe awọn ero meji kan. Bi mo ṣe de ileepo Oando to wa lagbegbe Berger, ọkunrin to fa baagi dudu dani kan juwọ silẹ fun mi, o loun n lọ si Ọgba, mo si gbe e.
“Bo ṣe wọle ni mo ti bẹrẹ si i gbooorun, oorun buruku ni. Emi tiẹ kọkọ n ṣe yẹyẹ pe ‘ẹyin ero ti mo gbe yii, ta lo so iso buruku yii ninu yin o’, gbogbo wọn si n rẹrin-in, ṣugbọn awọn naa dawọ bomu. Ba a ṣe tẹsiwaju, oorun yii tubọ gbalẹ si i, o n run bii oku nnkan kan. Nigba ti ko ṣee mu mọra mọ, awọn ero ni ki n duro niwaju ile ounjẹ Chicken Republic ta a fẹẹ kan, ki wọn le wo nnkan to n run ọhun, mo ni mi o le duro ninu okunkun yẹn o, nigba ti mi o mọ nnkan tonitọhun gbe sinu baagi tooorun ẹ n bu tii bẹẹ yẹn, o si ti n lọ si bii aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ, mo ni ki wọn jẹ ki n duro niwaju ileepo kan to wa nibudokọ Grammar School, l’Ojodu.
“Bi mo ṣe debẹ ti mo ri i pe awọn eeyan diẹ parojọ nibudokọ yẹn, mo kan tẹ bireeki ni, ni mo ba duro, ka le yẹ nnkan to da oorun abaadi ọhun silẹ wo. Ọkunrin Ibo kan wa ninu awọn ero yẹn toun naa fẹnu si i pe afi ki wọn yẹ ara wa wo. Ṣugbọn ọkunrin to gbe baagi dani yẹn kan nawọ owo si mi, o ni ki n gbowo mi, oun fẹẹ maa lọ ni toun. Eyi tubọ mu ki n fura si i, pe bawo lo ṣe le sanwo lai ti i debi to n lọ. Mo sọ fun un pe ọrọ owo kọ leyi, a fẹẹ mọ ohun to n run ni, ki lo wa ninu baagi ẹ.
“O ni baagi oun kẹ, bo ṣe bẹrẹ si i gbọn niyẹn, o ni ko si nnkan oorun nibẹ o, lo ba tu baagi naa, oriṣii baagi mẹta ọtọọtọ lo gbe kari ara wọn ninu baagi to fa lọwọ. Alakọọkọ, ewe tutu oriṣii kan lo di sibẹ. A ni ko tu ikeji, ewe naa lo di sibẹ, ẹkẹta n kọ, lo ba ta ku, ko fẹẹ tu u. Mo kan ja a gba mọ ọn lọwọ ni, ni gbogbo ẹru inu baagi naa ba tu da silẹ. Bi mo ṣe digbaju ru u niyẹn pe ko yaa bẹrẹ si i tu u ni kiamọsa, lo ba bẹrẹ si i tu u. Awọn bọisi ti wọn wa ni gareeji lasiko yẹn naa sun mọ wa, ni wọn ba fipa mu un pe lati tu baagi kẹta yẹn, tori bawọn naa ṣe sun mọ’bẹ ni wọn ti n gbọ oorun ti ko bara de, awọn obinrin kan tiẹ ti sa lọ tori oorun ọhun buru gidi ni.
“Bo ṣe n tu baagi kẹta yẹn, o to lailọọnu dudu bii mẹfa si meje to fi di oun nikan, o han pe ẹran tutu lo wa ninu ẹ, bo si ṣe n tu u lo bẹrẹ si i kigbe pe wọn ran oun ni o, ẹnikan lo fi i ran oun niṣẹ o, oun o mọ ohun to wa ninu ẹ o.
“Bo ṣe tu baagi naa bayii, a ri ẹran ara eeyan ti wọn ge lekiri-lekiri, a ri ifun, a ri eyin eeyan to so mọ erigi ti wọn ti ge, atawọn ẹya ara mi-in gbogbo.
“Ibẹ lawọn bọisi ti bẹrẹ si i din dundu iya fun, wọn n gba a nigbakuugba, igba to si jẹ iwaju teṣan ọlọpaa naa lo ti waye, awọn ọlọpaa jade wa, wọn ni wọn ba ni ki wọn maa lu u mọ, wọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, ni wọn ba mu un lọ atoun ati baagi ẹran eeyan ọwọ ẹ.”
Onimaruwa yii tun ṣalaye pe nigba tafurasi naa n tu baagi ẹ, awọn ri oogun apakokoro lẹbulẹbu to wọn kaakiri ara ẹsibiiti ọhun, boya lati mu ki oorun buruku naa walẹ lo ṣe ṣe bẹẹ. O ni lẹbulẹbu naa ti kọkọ fẹẹ mu oun nigan-an, tori oun ti fẹẹ ni ko maa lọ, nigba toun ro pe nnkan iṣegun ibilẹ lasan lo ko sibẹ to n run ni.
Ọkunrin naa tun fi anfaani yii dupẹ lọwọ ijọba Eko fun kikasẹ ti wọn kasẹ awọn ọlọkada nilẹ lawọn agbegbe kan l’Ekoo. O lara anfaani ẹ ni ti aṣiri oniṣẹẹbi to tu yii, tori to ba jẹ asiko tawọn ọlọkada ṣi n ṣiṣẹ ni, ọkada lafurasi ọhun iba gun, o si ṣee ṣe ki gbangba ma dẹkun mọ iwa ọdaran ọwọ rẹ bii eyi.
A tun bi i lere iru ẹni to ro pe afurasi naa jẹ, o si fesi pe: “Yoruba ni, Yoruba lo maa jẹ, tori bi wọn ṣe n fun un nigbaaju igbamu lo n kigbe ‘ẹ ma na mi, ẹ ma na mi o, wọn ran mi ni o, emi kọ o.’ Yoruba lo n sọ.
Nigba ta a pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, laago, o fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn taari afurasi naa sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba. O fi kun un pe awọn maa gbe awọn ẹya ara ti wọn ba lọwọ ẹ naa lọ fun ayẹwo lati fidi ododo mulẹ. O ni iwadii to lọọrin ti n lọ lori iṣẹlẹ yii, awọn yoo si gbe igbesẹ ofin lori ẹ.