Ori ni wọn ti yinbọn fun mi, awọn marun-un ṣi ku lakata awọn to ji wa gbe-Ọjọgbọn Agbaje

Monisọla Saka

Aja to rele ẹkun to bọ lọrọ Ọjọgbọn ileewe giga Fasiti ilu Ibadan atawọn akẹkọọ mẹta kan lati ileewe giga Poli Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, tori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe-gbowo ti wọn ji wọn gbe loju ọna Eko si Ibadan nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

Adigun Agbaje, to jẹ Ọjọgbọn imọ nipa iṣelu (Political Science), to si ti tun figba kan jẹ igbakeji giiwa Fasiti Ibadan, ti dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria fun aduroti wọn lasiko ti awọn agbebọn ji wọn gbe ni ọjọ Ẹti Furaidee, ọsẹ to kọja, ko too di pe o gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe naa lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii.

Lasiko to n fẹmi imoore han lo sọ pe, “Ojumọ mi-in lo tun mọ lonii, inu mi si dun lati wa laaye. Lalẹ ana ni mo gba idande lọwọ awọn ti wọn ji mi gbe lẹyin ti mo sun oorun ọjọ meji ninu aginju to wa laarin ipinlẹ Ọyọ ati Ogun. Bẹẹ lọkan mi wa lara awọn marun-un ti wọn ṣẹ ku sakata awọn ajinigbe naa: awọn ọdọmọbinrin meji, gende ọkunrin meji ati agbalagba kan. Lasiko ti wọn fẹẹ ji mi gbe yii, ori ni wọn ti yinbọn fun mi, amọ mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ja siku fun mi, ibi gilaasi mọto mi lọta ibọn yẹn ba jade lẹyin to da iho lu sibi fila ti mo de, to si tun da ọgbẹ nla si mi lori lọgangan ibi to ti ba mi. Mi o tiẹ kiyesi i, afi laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ti mo ri awọn ẹjẹ didi rigidi rigidi ninu fila mi.

 

Lọwọlọwọ bayii, mo n gba itọju ati ayẹwo lọwọ, fun idi eyi, o le ṣe diẹ ki n too ribi dupẹ lọwọ awọn ẹbi mi, titi kan awọn ana mi, ọrẹ atawọn ana awọn ọmọ mi, awọn ọrẹ temi naa, awọn alabaaṣiṣẹpọ mi atawọn ọmọ Naijiria patapata”.

 

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ Giiwa Fasiti Ibadan to wa lori ipo ati eyi to jẹ tẹlẹ, Ọjọgbọn Olufẹmi Bamiro, Ọjọgbọn Isaac Adewọle, Ọjọgbọn Idowu Ọlayinka ati Ọjọgbọn Kayọde Adebọwale. O tun fẹmi imoore rẹ han sawọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ ni Fasiti Ibadan, atawọn fasiti mi-in nile ati lẹyin odi, awọn akẹkọọ to ti gba iwaju ẹ kọja ri atawọn to n kọ lọwọ bayii, awọn bii Ọgbẹni Fisayọ Ṣoyọmbọ, fun atilẹyin alailẹgbẹ ati ọwọ oore ti wọn na si awọn mọlẹbi ẹ. O tun dupẹ pupọ lọwọ awọn ijọba, awọn ọmọ ogun ilẹ wa atawọn ẹṣọ alaabo mi-in fun ipa takuntakun wọn.

O ni, “Mo dupẹ pupọ fun akitiyan yin lati ri i daju pe idunaadura yin ṣee ṣe ti wọn fi tu mi silẹ nirọlẹ ana. Lẹẹkan si i, ẹmi mi wa pẹlu awọn ti mo fi silẹ lakata awọn ajinigbe naa, o ṣee ṣe kẹ ẹ ma ribi pe mi bayii, amọ tawọn dokita ba ti da mi silẹ, ma a dupẹ lọwọ ẹni kọọkan yin pata”.

 

Ninu ọrọ tiẹ, Ọjọgbọn Fẹmi Bamiro ni Ọlọrun lo ni gbogbo ogo, bẹẹ lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn wa ninu ikanni ti wọn ti pe fun iranlọwọ, ti wọn si sa ipa wọn niwọnba akoko perete ọhun lati sanwo itusilẹ fawọn ajinigbe naa. O ni pẹlu iriri oun latara ọrọ to ṣẹlẹ yii, oun ti waa ri i daju bayii pe gbogbo wa la daran, afi ki Ọlọrun gba wa.

Leave a Reply