Ọpọ eeyan ku, aimọye dukia ṣofo, ninu ijamba ina to ṣẹlẹ l’Ekoo

Jọkẹ Amọri

Titi di asiko ta a n kọ iroyin yii ni awọn panapana atawọn ẹṣọ alaabo gbogbo n gbiyanju lati pa ina ọmọ ọrara kan to fẹju kẹkẹ, nibi ti ọpọ eeyan ti ẹnikẹni ko ti i le sọ iye wọn ha si, lọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla yii.

Ina naa to bẹrẹ nibi ile nla kan ti banki Keystone, to wa lagbegbe Adeọla Ọdẹku, ni Erekuṣu Eko  atawọn ileeṣẹ mi-in wa ni wọn lo fẹmi ọpọ eeyan ṣofo.

Awọn ileeṣẹ panapana atawọn alaanu kan la gbọ pe wọn n gbiyanju lati gbe awọn eeyan jade ninu ile to n jona yii.

Niṣe ni ọkọ ọlọpaa ti wọn paaki siwaju ile iṣe yii gbina, to si jo gburugburu, bẹẹ lawọn mọto mi-in ti ọn paaki sita ibẹ.

Ko ti i sẹni to le sọ ohun to ṣokunfa ina ọhun, ṣugbọn ohun ta a gbọn ni pe ọpọ eeyan ni wọn lo ku, ti ọkẹ aimọye dukia si ba iṣẹlẹ naa lọ.

 

Leave a Reply