Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Beeyan ba jẹ ori ahun, to ba de ibi ti ọkọ akoyọyọ kan ti tẹ ọlọpaa meji pa ni kutukutu owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla yii, l’ Ado-Ekiti, ko si ki tọhun ma ṣomi loju.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni awọn ọlọpaa meji ti wọn n gbe niluu Iworoko-Ekiti yii, ni wọn n bọ nibi iṣẹ wọn to wa ni oju ọna to lọ si Iyin-Ekiti, laaarọ ọjọ Aje yii, ki iṣẹlẹ naa too waye.
ALAROYE gbọ pe Ifaki-Ekiti ni ọkọ akoyanrin naa ti n bọ, o n lọ si adugbo Adebayọ, nibi to ti fẹẹ yi si ọna to lọ si ọsibitu ijọba to wa loju ọna naa ni ọrọ ti yiwọ, to si lọọ kọ lu awọn ọlọpaa to wa lori ọkada ti wọn n lọ jẹẹjẹ wọn, to tẹ wọn pa.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa meji naa wa lori ọkada, wọn n bọ lati Iworoko-Ekiti, ti wọn n lọ si Ado-Ekiti, ki ọkọ akoyọyọ naa too gba oju ọna miiran lati yago fun iṣẹ ọna ti wọn n ṣe lọwọ ni agbegbe naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ” iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ laaarọ kutukutu ọjọ Mọnde, nigba ti awọn ọlọpaa meji naa n bọ nibi iṣẹ wọn.
“Awọn ọlọpaa naa n lọ loju ọna tiwọn, awakọ akoyọyọ naa fẹẹ sọda si apa keji ọna lati ya fun awọn to n ṣiṣẹ loju ọna naa, lasiko naa lo kọ lu wọn, ti awọn mejeeji si ku loju-ẹṣẹ.
‘‘Awọn agbaṣẹṣe naa ti kọkọ gbe patako ajuwe kan si oju ọna naa lati sọ fun awọn awakọ pe iṣẹ akanṣe kan n lọ lọwọ loju ọna naa.’
A gbọ pe awakọ akoyọyọ naa ti wa latimọle ọlọpaa, bẹẹ ni wọn si ti gbe oku awọn agbofinro mejeeji naa pamọ si ileewosan ẹkọṣẹ Yunifasiti ijọba ipinlẹ Ekiti.
Ọga agba ẹṣọ ojupopo nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Oluṣọla Joseph, ti kilọ fawọn awakọ pe ki wọn maa din ere wọn ku lakooko ti wọn ba wa loju ọna.