‘Tori owo ti mo fẹẹ ji ninu akaunti iyawo baba mi lemi atawọn ọrẹ mi ṣe pa a’

Faith Adebọla

Ọdaju afurasi ọdaran ẹni ogun ọdun kan, Ekenedilichukwu Okeke, ti jẹwọ pe niṣe loun mọ-ọn-mọ bẹ awọn ọrẹ oun lọwẹ pe ki wọn ba oun gba miliọnu kan Naira (N1 million) jade ninu akaunti iyawo baba oun, Abilekọ Theresa Okeke, o loun nilo owo naa lati fi sanwo ati wọ fasiti, oun si mọ pe toun ba beere lẹrọ, oloogbe yii ko ni i fun oun, idi niyẹn toun fi pa a.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni wọn pa mama ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta to n ṣiṣẹ oluṣiro owo pẹlu ajọ eleto ikaniyan ilẹ wa, National Population Commission (NPC), ọhun, sinu ile rẹ to wa l’Ojule kẹrin, Opopona Umuziocha, niluu Awka, nipinlẹ Anambra. Wọn ni niṣe ni wọn yin obinrin naa lọrun pa laajin oru.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, ṣafihan awọn afurasi ọdaran mọkandinlogun kan tawọn ọtẹlẹmuyẹ n tọpinpin oriṣiiriṣii ẹsun ti wọn fi kan wọn lọwọ, awọn amookunṣika meji ti wọn da ẹmi oloogbe yii legbodo si wa lara wọn.

Boroboro bii ajẹ to jeepo ọbọ ni Ekenedilichukwu n ka lasiko tawọn oniroyin n beere ọrọ lọwọ ẹ, o ni:

“Mo ṣẹṣẹ pari idanwo JAMB mi ni, mo n ṣe awọn iṣẹ keekeeke ki n le tuwo jọ lati sanwo wọle si yunifasiti ti wọn ba mu mi. Koda, wọn ba mi waṣẹ sọdọ ajọ eleto ikaniyan, mo ṣiṣẹ pẹẹpẹẹpẹẹ kan pẹlu wọn ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin. Ọdọ mọmi yii ni mo n gbe.

“Laipẹ yii ni ede aiyede waye laarin emi pẹlu wọn, wọn ni mo ṣẹ awọn. Inu bi wọn gan-an, mo si bẹ wọn pe ki wọn ma binu. Mo ro pe wọn ti fori ji mi ni, tori mo bẹ wọn gidigidi. Ṣugbọn lọjọ keji ni wọn pe mi, wọn ni ki n kẹru mi, ki n kuro lọdọ awọn.

“Mo pe Dadi mi, iyẹn ọkọ wọn, lori aago ki n le ṣalaye fun wọn, ṣugbọn wọn ko gbe aago wọn. Ni mo ba pe ẹgbọn mi ọkunrin, mo si sọ ohun to ṣẹlẹ fun un.

Nigba to ya, mo pe awọn ọrẹ mi kan, mo sọ fun wọn pe ki wọn kọ mi lọgbọn ta a le fi rowo gba lọwọ mama to le mi yii, tori owo wọn ni mo ti gboju le lati fi i sanwo ileewe mi to ba to asiko ati wọle.

“Ọgbọn ati gbowo yii la n da lọwọ ti mama naa fi digbo lulẹ, ti wọn si ku lojiji.

“Mo kabaamọ ohun to ṣẹlẹ yii, adua mi ni pe k’Ọlọrun dari ji mi, kijọba naa si ṣiju aanu wo mi. Mi o paayan ri laye mi,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Ọkan ninu awọn ọrẹ ẹ ti wọn jọ gbimọ-pọ ṣiṣẹ buruku naa, Peter Jideofor, tọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ba ṣalaye ẹnu ẹ, o ni:

“Iṣẹ orin ni mo n ṣe, ‘musician’ ni mi. Emi ni mo faṣọ di oloogbe yii lẹnu lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, ko ma baa lọgun le wa lori. A o ni i  lọkan lati gbẹmi ẹ o, ka lo ti fun wa ni nọmba aṣiri to fi n gba owo ninu kaadi rẹ, iyẹn PIN ẹ ni, a o ni i pa a.

“Ọrẹ mi yii lo waa sọ fun mi pe ija kan waye laarin oun ati iyawo baba ẹ, mọmi ẹ lo maa n pe wọn, o si ni ki n ran oun lọwọ lati gba miliọnu kan Naira lọwọ ẹ. A jọ di i ni nnkan bii aago meji oru, pẹlu awọn ọrẹ wa mi-in, a wọle tọ mama naa lọ, a so o lọwọ atẹsẹ.

“Nigba to fẹẹ maa lọgun, emi ni mo so o lẹnu pa, aṣọ kan ni mo fi di i lẹnu pinpin, bo ṣe di pe ko mi mọ niyẹn. Igba yẹn lemi jade kuro nibẹ ni temi, tori a o ni in lọkan lati paayan.  Bi mo ṣe n kuro nibẹ lọjọ yẹn, mo sọ fawọn to ku pe ki wọn maa yọju si mama ni ọgbọn iṣẹju iṣẹju, boya o le pada ji saye, tori mi o lero pe o le ku tuẹ bẹẹ yẹn.

“Igba tilẹ mọ ni wọn pada sọ fun mi pe o ti ku fin-in-fin-in. Aya gbogbo wa ja nigba ta a ri nnkan to ṣẹlẹ, mi o le jade nile titi tawọn ọlọpaa fi de, ti wọn waa mu mi.

Iru ẹ ko ṣẹlẹ si mi ri, igba akọkọ leyi. Mi o niyaa ati baba laye mọ, ọmọ orukan ni mi, iṣẹlẹ yii ka mi lara o.” Bẹẹ loun naa sọ.

Ṣa,  Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Anambra, CP Echeng Echeng,  ṣalaye pe irọ buruku tawọn apaayan yii kọkọ gbe kalẹ ni pe awọn adigunjale kan ni wọn ya wọle naa loru, ti wọn pa mama ọhun. Ṣugbọn nigba tiṣẹ iwadii tẹsiwaju ni wọn jẹwọ pe awọn lawọn pa a, wọn ni miliọnu kan Naira lawọn fẹẹ ba ọrẹ awọn gba lọwọ ẹ tọrọ naa fi ja siku.

Kọmiṣanna lawọn ṣi n ṣewadii, awọn si ti n dọdẹ awọn yooku to lọwọ ninu iwa ọdaran nla yii. O ni gbogbo wọn lo maa jẹyan wọn n’iṣu niwaju adajọ laipẹ.

 

Leave a Reply