Gbenga Amos, Abẹokuta
Bi ki i baa ṣe yiyọ Ọlọrun, niṣe loku iba di meji nileewosan ijọba apapọ, iyẹn Federal Medical Centre, to wa ni Idi-Aba, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, pẹlu bi baba kan ati ọmọ rẹ ṣe wọ dokita mọra, ti wọn si n fun un ni igbaju ati igbamu, lẹyin to kede pe iyawo ọkunrin naa to jẹ ẹni ọdun mẹtalelaaadọta ti wọn gbe wa si ileewosan naa ti ku.
Alaga ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ogun, Dokita Kunle Ashimi, to ṣalaye ọrọ naa fawọn oniroyin sọ pe o ṣe diẹ ti obinrin yii ti ni aisan ọkan. Ileewosan kan lo si wa tẹlẹ, o jọ pe nigba ti apa awọn yẹn ko ka a mọ ni wọn ni ki wọn maa gbe e lọ si ọsibitu ijọba naa.
Nigba ti wọn gbe e de, awọn dokita ṣe ayẹwo rẹ, wọn si ri i pe aisan ọkan naa ti wọ ọ lara gidigidi, iyanu Ọlọrun nikan lo si ku ti obinrin naa fi le tun jẹ alaaye pada, nitori aisan naa ti kọja bẹẹ lara rẹ. Dokita ṣalaye ohun ti wọn ri yii ati akọsilẹ ti dokita to ni ki wọn maa gbe e bọ ni ọsibitu naa kọ. Wọn sọ fun awọn mọlẹbi oloogbe yii pe aisan ọkan naa ti de ipele to gangun si iku, o ti wọ ọ lara gan-an. Ṣugbọn dokita yii sọ pe awọn naa gbagbọ ninu iṣẹ iyanu Ọlọrun, nitori awọn ti ri ẹni to ni iru aisan bii ti obinrin yii, nigba tawọn si bẹrẹ itọju fun un, iyanu Ọlọrun ṣẹlẹ, o si gbadun. Wọn ni eyi ni awọn fi bẹrẹ itọju fun obinrin yii naa pe ki awọn maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ.
Ṣugbọn ọrọ pada yiwọ nigba to di bii aago meji oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kejila yii, obinrin naa mi imi ikẹyin. N ni Dokita Pẹlumi Somorin ba jade lati waa tufọ iku rẹ fun awọn mọlẹbi rẹ, iyẹn ọkọ obinrin naa ati ọmọ rẹ ọkunrin kan.
Eyi ti awọn mọlẹbi yii iba si fi gba f’Ọlọrun, niṣe ni wọn fi onija silẹ o, ni wọn ba gba alapẹpẹ mu. Dokita yii ni baba atọmọ kọju si, ni wọn ba bẹrẹ si i gba a loju-nimu, bẹẹ ni wọn n rọjo ẹṣẹ fun un. Eyi ko si yọ ọkan ninu awọn nọọsi to wa nitosi naa silẹ, wọn fi lilu da batani si oun naa lara. Bi o ba si jẹ yiyọ Ọlọrun, niṣe loku iba di meji lọsibitu yii lọjọ naa, nitori awọn eeyan naa ko kọ ohunkohun to le ṣẹlẹ si dokita ti wọn n lu bii aṣọ ofi yii.
Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa teṣan Kemta ti wọn sare ranṣẹ si. DPO teṣan naa atawọn ọmọọṣẹ rẹ ni wọn wa si ọsibitu ọhun, ṣugbọn pẹlu pe awọn agbofinro wa nibẹ naa, wọn ni ọmọ obinrin to doloogbe yii ko dawọ duro, niṣe lo tu n na dokita naa lọ.
Lẹyin ọpọlọpọ wahala ni wọn mu baba atọmọ yii pẹlu dokita ti wọn sọ di ilu bẹmbẹ ti wọn n lu nilukulu ati nọọsi pẹlu awọn ẹlẹrii lọ si teṣan wọn, ti onikaluku si ṣalaye bọrọ ọhun ṣe ṣẹlẹ gan-an.
Dokita Ashimi waa rọ awọn araalu lati yee kọju ija si awọn eleto ilera tabi lati maa fiya jẹ wọn. O fi kun un pe eyi to ṣẹlẹ yii ko ni i da lori ẹbẹ lasan, ti awọn yoo si gbagbe ọrọ naa. O ni lati maa fiya jẹ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti di ohun to n lọ kaakiri agbaye, ti ẹnikẹni ko si ti i ri nnkan kan ṣe si i.
Ṣe ma foko mi ṣọna, ijọ kan la a kọ ọ, eyi ni alaga awọn dokita naa fi sọ pe sọ pe ki ẹnikẹni ma ro pe oun maa waa bẹ awọn pe ki awọn gbagbe ọrọ naa gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe sẹyin, bo ti wu ki ẹni bẹẹ lagbara to. O ni gbogbo igbesẹ labẹ ofin lawọn maa gbe, bẹẹ lo ni awọn ti n mura lati gbe ọrọ naa lọ sile-ẹjọ, ki iya ma baa jẹ awọn oṣiṣẹ awọn gbe.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii naa ni awọn mọlẹbi kan ki dokita ati nọọsi kan mọlẹ ni oṣibitu ijọba to wa niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ti wọn si lu wọn bii kiku bii yiye, lẹyin ti eeyan wọn ti wọn gbe wa sọsibitu naa ku. Bo tilẹ jẹ pe awọn dokita yii ti sọ fun wọn pe ki wọn maa gbe e lọ si ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun ti ileewe giga fasiti kan to wa nipinlẹ naa ko too di pe awọn mọlẹbi yii ki ijafara bọ ọ, ti ọkunrin naa si pada ku.