Jọkẹ Amọri
Bẹ ẹ ṣe n ka iroyin yii, ilu Mecca, lorileede Saudi Arabia, ni oṣere ilẹ wa to maa n ṣe awọn fidio keekeeke ti wọn n pe ni (skit) lati fi dẹrin-in pa awọn eeyan, Abdulgafar Ahmed Abiọla ti gbogbo eeyan mọ si Cute Abiọla, wa bayii, nibi to ti lọọ ṣe ẹsin lasiko Umrah to n lọ lọwọ yii.
Igba akọkọ niyi ti ọmọkunrin naa yoo de Mecca gẹgẹ bo ṣe sọ. Ki i ṣe pe ti yoo de Mecca nikan, igba akọkọ niyi ti yoo kuro ni orileede Naijiria lọ si ibikibi lagbaaye.
Ọmọkunrin to ti di Oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ Kwara bayii sọ pe majẹmu ti oun ba Ọlọrun da ni pe igbakugba ti oun ba maa kuro ni orileede Naijiria lọ si ibikibi lagbaaye, ibi akọkọ to maa wu oun lati kọkọ lọ ni Mecca.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kejila yii, ni oṣere yii gbe fọto rẹ niluu Mecca si ori ikanni agbọrọkaye rẹ, to si kọ ọ sibẹ bayii pe, ‘‘O ti wa ninu erongba ọkan mi latọjọ to ti pẹ pe nigbakugba ti mo ba kuro ni ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ wa ti mo ti n ṣiṣẹ tẹlẹ, ti mo ba si ṣetan lati maa rin-irinajo kuro ni orileede Naijiria lọ si awọn ilẹ mi-in, awọn ibi meji to wu mi lọkan lati kọkọ lọ ni Mecca ati Medina, ki n le lọọ fọpẹ fun Ọlọrun Alagbara fun irinajo mi lati ọjọ yii wa, ki n tiẹ too lọ si ibikibi mi-in lagbaaye.
‘‘Lẹẹkan si i, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to jẹ ki eleyii ṣee ṣe fun mi. Ilu Medinah ni mo wa yii, ni Saudi Arabia, ibi akọkọ ti mo kọkọ rin irinajo lọ nigba ti mo jade ni Naijiria.
‘‘Awọn alatilẹyin mi ni agbara mi to pọ ju lọ, mo si gbadura pe ẹ wọn yoo ni iriri ọdun tuntun to kun fun ibukun pẹlu oore-ọfẹ Ọlọrun.
Mo ki gbogbo yin ku ọdun, mo si fi ẹmi imoore han si gomina ipinlẹ Kwara ati ileeṣẹ ọmọ oju omi ilẹ wa’’.
Latigba ti Cute Abiọla bi wọn ṣe maa n pe e ti gbe ọrọ yii si ori ikanni rẹ ni awọn ọrẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ti n ki i ku oriire, ti wọn si n gbadura fun un pe eyi to lọ yii ko ni i jẹ alọmọ fun un.
Nibikibi tẹ ẹ ba ti ri Cute Abiọla bayii, afi kẹ ẹ yaa fi alaaji kun orukọ rẹ.