Fẹmi Iyanda, London
Iku ti mu Ọmọọba Anthony Adegoke Aladesanmi, ti i ṣe akọbi kabiyesi Ewi tiluu Ado-Ekiti ana, lọ. Arẹmọ ọba naa ti faye silẹ, o ti gbọrun lọ. Ilu Florence, lorileede Italy, ni ọkunrin yii ti jade laye.
Gege bi atẹjade ti Ẹgbẹ Ọmọ Yoruba lorilẹ-ede Italy, YNCI, labẹ akoso Aarẹ wọn, Ọmọọba Kọlawọle Ọladele, fi sita fawọn oniroyin, o ni ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin (69) ni oloogbe yii lasiko to faye silẹ.
Ọdun 1976, l’Ọmọọba Aladesanmi rin irinajo lọ sorileede Italy, nibi to ti kawe yege gẹgẹ bii onimọ nipa eto ọgbin nilẹ olooru (Doctorate in Tropical Agriculture), latigba naa lo si ti n gbe lorileede Italy.
Ọmọọba Aladesanmi jẹ ọkan pataki lara awọn aṣaaju ti wọn da ẹgbẹ ọmọ Yoruba orilẹ-ede Italy silẹ ni ẹkun Florence. Bakan naa lo ṣiṣẹ takun-takun ninu idagbasoke ẹgbẹ naa gẹgẹ bii ẹri ti Aarẹ ẹgbẹ yii ni ẹkun Toscana, Iyaafin Oliseh, fidi rẹ mulẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, Ogunjọ, oṣu yii, ni wọn yoo sinku Ọmọọba to doloogbe yii niluu Prato, lorileede Italy. Iyawo, ọmọ, ọmọọmọ ati ẹbi ni arẹmọ ọba yii fi saye lọ. Bakan naa ni apapọ ẹgbẹ ọmọ Yoruba lorileede Italy n ṣeleede lẹyin ọkan ninu awọn aṣaaju wọn.