Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Yẹmi Ọṣinbajo atiyawo ẹ, Dọlapọ Ọṣinbajo, naa ti ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede rere lati dibo yan adari tuntun, gẹgẹ bii eto idibo aarẹ, atawọn aṣofin ṣe n waye jake-jado orilẹ-ede Naijiria.
Ọṣinbajo atiyawo ẹ, tawọn mejeeji wa lati Ikenne, ti dibo wọn ni ibudo idibo kẹrinla, agbegbe Egunrege, ijọba ibilẹ Ikenne nipinlẹ Ogun.
Ni nnkan bii aago meje aarọ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun lawọn ajọ eleto idibo INEC ti de sibẹ, ti eto ayẹwo orukọ awọn oludibo si bẹrẹ laago mẹsan-an ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn.
Aago mẹwaa aarọ ku iṣẹju mẹfa, ni Igbakeji Aarẹ atiyawo ẹ de si ibudo idibo wọn, ni kete ti wọn yẹ orukọ wọn wo tan, ti wọn si lo ẹrọ to n ṣayẹwo awọn oludibo fun wọn tan, ni wọn tẹka ni deede aago mẹwaa aarọ.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to dibo tan, Ọṣinbajo ni inu oun dun, bẹẹ lori oun ya pẹlu bi wọn ṣe ṣeto ohun ni gbogbo ibudo idibo oun ti ko fi si wahala tabi iwa janduku kankan nibẹ.