Ko si adehun kankan laarin Tinubu ati Makinde lati ṣatilẹyin fun un lori idibo gomina

Ọlawale Ajao, Ibaadan

Igbimọ to n ṣe ipolongo fun ipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ti ṣọ pe ko si ajọsọ ọro tabi ipade kanakn laarin aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, aẹanjinnia Ṣeyi Makinde pe ọkunrin naa ni ki ẹgbẹ awọn dibo fun.

Nitori ipade to waye laarin aarẹ ti awọn ọmọ Naijiria ṣẹṣẹ dibo yan ọhun ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe adehun kan wa laarin awọn mejeeji, paapaa, lori idibo aarẹ to kọja yii, ati idibo gomina to maa waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2023 ta a wa yii pe Makinde ni awọn ẹgbẹ APC maa ṣatilẹyin fun.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ba wọn kopa ninu ipade naa, to jẹ awọn mejeeji ni wọn mọ ohun ti wọn jọ sọ, sibẹ, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe niṣe lawọn mejeeji jọ ṣadehun lati jọ ran ara wọn lọwọ lasiko idibo gomina ati idibo aarẹ.

Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ to polongo idibo fun Aṣiwaju Tinubu nipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Nikẹ Ajagbe, ti sọ pe ko si adehun kankan laarin aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa pẹlu gomina ipinlẹ Ọyọ.

Obinrin oloṣelu naa ṣalaye pe ko si nnkan to jẹ babara ninu abẹwọ ti Tinubu ṣe si Makinde. O ni gbogbo ipinlẹ ti Tinubu lọ fun ipolongo idibo rẹ, gomina ipinlẹ naa lo kọkọ maa n ṣabẹwo si, paapaa, awọn gomina maraarun ti wọn ko fara mọ bo ṣe jẹ pe ara iha Oke-Ọya lẹgbẹ oṣelu Alaburada fa kalẹ gẹgẹ bii alaga apapọ ati oludije fun ipo aarẹ.

Lẹyin esi idibo aarẹ to waye lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, la gbọ pe Gomina Makinde ṣepade pẹlu awọn to dupo sẹnetọ ati aṣoju-ṣofin, to si bẹ wọn lati ṣatilẹyin fun un ki o le wọle idibo gomina to n bọ lọjọ kọkanla, oṣu yii.

Ninu ipade ọhun naa ni wọn ni gomina yii ti sọ pe oun yoo fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ APC lọjọ iwaju.

Abilekọ Ajagbe tẹsiwaju pe Makinde ko ṣatilẹyin fun Tinubu nibi idibo aarẹ to kọja yii, nitori ko sigba kankan ti ọkunrin naa sọ ọ sita pe Tinubu ni kawọn eeyan dibo fun.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “gbogbo ariwo ti Makinde n pa kiri pe Aṣiwaju Tinubu ti sọ oun di aayo laarin awọn to n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ, irọ pata ni. Aṣiwaju ki i fi ẹgbẹ oṣelu ẹ ṣere, ko le fi ọmọ ẹgbẹ oṣelu ẹ silẹ ko maa ṣatilẹyin fun ẹni to n dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu mi-in laelae”.

Leave a Reply