Ẹ maa na gbogbo owo atijọ ati tuntun lọ titi dipari ọdun yii-Ile-ẹjọ to ga ju lọ

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa ti paṣẹ pe nina lowo, ko si aṣadanu lara Naira, wọn ni karaalu maa na igba Naira, ẹẹdẹgbẹta Naira, ati ẹgbẹrun naira atijọ ati tuntun lọ nifẹgbẹkẹgbẹẹ, titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni idajọ naa waye lori ẹjọ ti awọn ipinlẹ mẹta kan, Kogi, Kaduna, ati Zamfara, pe ta ko ijọba apapọ latari gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2023, ti banki apapọ ilẹ wa, CBN, paṣẹ pe nina lawọn awọn owo atijọ naa yoo dopin, owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ rẹ laro oriṣiiriṣii ni wọn ni kawọn eeyan maa na.

Ọrọ naa mu inira ati idarudapọ ba araalu, titi di ba a ṣe n sọ yii si ni pakaleke ati aifararọ ṣi n ba awọn eeyan finra lori gbedeke naa, bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti kede pe kawọn eeyan ṣi maa na igba Naira atijọ ati tuntun niṣo titi di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ti owo atijọ yoo di kọndẹ, amọ ni ti ẹẹdẹgbẹta Naira, iyẹn faifu ọndirẹẹdi (N500), ati ẹgbẹrun Naira, wan taosan (N1,000), o leyii ti wọn rẹ laro tuntun lara awọn eleyii nikan lawọn eeyan gbọdọ maa na.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ John Okoro to ka ipinnu tawọn adajọ mẹsẹẹsan naa fẹnu ko le lori jade, sọ pe ko boju mu, ko si bofin mu pẹlu, bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe paṣẹ fun Ọga agba banki apapọ ilẹ wa pe ki wọn fi gbedeke iye teeyan le gba ninu asuwọn rẹ ni banki tabi lẹnu ẹrọ ipọwo, ATM lede. Wọn ni aṣẹ naa ta ko ẹtọ araalu lori dukia wọn, eyi to wa ninu iwe ofin ilẹ wa, tori ẹ, ile-ẹjọ naa wọgi le gbedeke iye owo gbigba ọhun, wọn ni iye to ba wa kaluku lo le gba, ibaa jẹ araalu tabi olokoowo.

Wọn tun ni gbedeke lori nina owo atijọ ati awọn ilana tijọba apapọ gbe kalẹ lori eto pipaarọ Naira ọhun ko yatọ si aṣẹ onikumọ, wọn lo ti fẹẹ jọra pẹlu aṣẹ kan-n-pa, ati iṣakoso ‘ohun-mo-ba-sọ-labẹ-ge’, eyi si lodi si eto ijọba démokiresi patapata.

Bakan naa ni kootu ti ẹjọ maa n pẹkun si ọhun koro oju si bijọba apapọ ko ṣe tẹle aṣẹ ti wọn pa lọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun yii, pe ki wọn ṣi jẹ karaalu maa na gbogbo owo atijọ ati tuntun lọ titi tawọn fi maa gbọ ẹjọ naa, wọn niwa tijọba Buhari hu yii ku-diẹ-ka-a-to, wọn niwa ta-ni-maa-mu-mi gbaa ni.

Ni ti awijare Minisita feto idajọ nilẹ wa, Abubakar Malami, eyi to fi sọ pe ile-ẹjọ to ga ju lọ ko laṣẹ lati ṣepinnu lori ẹjọ Naira ti wọn ko wa siwaju rẹ ọhun, ile-ẹjọ naa ni ajadi apẹrẹ ni Malami n pọnmi si pẹlu awijare rẹ, wọn da a nu bii omi iṣanwọ, wọn laroye ti ko bofin mu lo ṣe.

C

Leave a Reply