Monisọla Saka
Oku ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹrin to sọnu, Eleazar Ishiya, ni wọn pada ri ninu koto kan nitosi ile ounjẹ igbalode Mr. Biggs, to wa lagbegbe Jabi, Abuja, lẹyin odidi ọjọ mẹta ti wọn ti kede pe wọn n wa a.
Ẹni kan ninu ẹbi awọn ọmọ naa ni, lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn ti kede pe wọn n wa ọmọdekunrin naa laduugbo Filin Ball, Jabi Daki Biyu, ti wọn si pada ri oku rẹ lẹyin ọjọ kẹta.
Ẹni kan to wa nibi ti wọn ti n gbe oku ọmọ naa, Joel Joseph, ni, “Nigba ta a ri oku ọmọ naa ninu koto ọhun, iya baba ẹ kọkọ fẹẹ bẹ sinu ẹ, ṣugbọn mo di iya naa mu, mo si wọ wọn si ẹgbẹ kan. Emi ni mo bẹ sinu koto yẹn, nibi ti oku ọmọ yẹn ti bẹrẹ si i jẹra. Wọn ti ge ahọn, oju omuṣu ati nnkan ọmọkunrin ẹ lọ, bẹẹ ni wọn tun yọ oju ẹ mejeeji lọ.
Ohun to daju ni pe awọn apaniṣowo ni wọn da ẹmi ọmọ naa legbodo, ti wọn si foru boju lati waa sọ ọ sinu koto ta a ti ba a yẹn”.
Iya ọmọkunrin to ku yii, Arabinrin Precious Ishaya, ṣapejuwe rẹ bii ọmọ to ja fafa, o jẹ akẹkọọ kilaasi jẹle-o-sinmi (Nursery one), oun nikan naa lo si wa lọwọ awọn obi ẹ lasiko iku ẹ yii.
Iya ẹ ni, “Lọjọ Ẹti, Furaidee, tiṣẹlẹ yii maa waye, mo ṣẹṣẹ fẹẹ wẹ fun Eleazar ni. Lo ba mu Naira mẹwaa, pe oun fẹẹ lọọ fi ra suuti nitosi ile, ibi ta a mọ mọ naa niyẹn. Latigba naa la si ti n wa a”.
Nigba to n sọrọ lori bi iku ọmọ naa ṣe ri lara rẹ, o ni, “Iku ẹ o fi bẹẹ ka mi lara, ṣugbọn iru irora ti yoo jẹ ko too di pe ẹmi bọ lara rẹ lo n ṣe mi. Mo ti fi ọrọ mi le Ọlọrun lọwọ. Emi o mọ awọn oṣika ọhun o, nitori mi o loju lẹyin, ki i si i ṣe pe mo wẹju lati mọ wọn. Ẹjẹ ọmọ yẹn maa da wọn laamu nitori ọmọde ti ko mọ nnkan kan ni. Kawọn funra wọn gan-an gba pe awọn ti ku. Ẹmi mi o tilẹ gbe e lati wo iwọnba ara ẹ yooku ti wọn gbe de. Igba to ya ni mo ṣe ọkan giri ti mo ri i ninu fọto”.