Faith Adebọla
Bi wọn ba ni ki wọn kọkọ lọọ ṣayẹwo sọpọlọ afurasi ọdaran kan ti wọn porukọ ẹ ni Ozo Uba yii, lati mọ boya nnkan ti fẹ si i lọpọlọ, ọrọ naa to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ. Omi iwẹ ni wọn lo dija silẹ laarin ọkunrin to yan iṣẹ alapata maaluu laayo yii ati iyawo rẹ, Abilekọ Sandra James, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, lo ba lọ ọbẹ gba lọwọ obinrin naa, ere ni awada ni, niṣe lo gun iyawo rẹ pa, to si kun un bii ẹran.
Aṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin yii, niṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye nile ti tọkọ-taya naa n gbe, niluu Warri, nipinlẹ Delta.
A gbọ pe ọrọ omi gbigbona ti baale ile yii loun fẹẹ fi wẹ lo daja silẹ. Wọn ni iyawo rẹ n dana ounjẹ lọwọ ni nigba ti ọkọ rẹ dari de lati ọja Igbudu, niluu Warri, nibi to ti n ṣiṣẹ alapata rẹ. Lo ba bẹ iyawo naa pe ko jẹ koun bu diẹ lara omi gbigbona to wa lori gaasi idana wọn lati da a mọ omi tutu toun fẹẹ fi wẹ. Wọn ni ọrinrin gbode lalẹ ọjọ naa, ọkọọyawo yii si fẹẹ fomi to lọwọọrọ wẹ.
Amọ niṣe ni iyawo rẹ fariga, ko gba fun un lati bu lara omi naa, o fẹsun kan ọkọ rẹ yii pe ko fi owo gaasi silẹ, ko si fowo ounjẹ silẹ nile, ko mọ bi gaasi idana ṣe de, tori eyi, oun ko le gba a laaye lati bu omi gbigbona naa, n lọrọ ba dija laarin wọn.
Nibi ti ọkọ ti fẹẹ fogboju bu omi yii niyawo rẹ ti lọọ fa ọbẹ yọ si i lati ileedana wọn, o si halẹ mọ ọkọ rẹ pe niṣe loun yoo gun un pa to ba fi le bu lara omi gbigbona naa. Amọ nigba ti ọkunrin naa raaye ja ọbẹ ọhun gba mọ iyawo rẹ lọwọ, ko beṣu bẹgba rara, niṣe lo fi i gun un, o si gun un kaakiri ni, eyi to mu kobinrin naa ṣubu lulẹ ninu agbara ẹjẹ.
Wọn ni bi baale ile yii ṣe ri ohun to ṣẹlẹ lo sare gbe iyawo rẹ digbadigba lọ sileewosan aladaani kan to wa nitosi.
Amọ b’oun ṣe kọri sileewosan, niṣe ni ọmọ wọn obinrin ti iṣẹlẹ yii waye niṣeju rẹ kọri si teṣan ọlọpaa kan ti ko fi bẹẹ jinna sile wọn, o lọọ fẹjọ baba rẹ sun, eyi to mu kawọn agbofinro tẹle e lọ sile naa. Wọn ri agbara ẹjẹ to wa nibi ti tọkọ-taya naa ti wọya ija, lati ibẹ ni wọn ti lọọ sọsibitu ti wọn gbe mama rẹ lọ, ibẹ si ni wọn ti sọ fun wọn pe ẹpa ko boro mọ, iyaale ile naa ti dakẹ.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa fi pampẹ ofin gbe baba alapata yii, lo ba dero ahamọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lori ikanni abẹyẹfo, tuita rẹ.
O kọ ọ sibẹ pe, “Afurasi kan, Ozo Uba, to jẹ ọkọ Sandra James, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ni aawọ laarin ara wọn, o si ti fi ọbẹ gun iyawo naa ṣakaṣaka titi to fi ku. Ileewosan nibi to ti n gba itọju lọwọ lo ku si. Afurasi naa ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, iwadii si ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii” gẹgẹ bo ṣe wi.