Adewale Adeoye
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kan ti wọn n pe ni ‘ Trade Union Congress’ (TUC), nilẹ wa, Ọgbẹni Festus Osifo, ti sọ pe ki Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, tete da owo epo bẹntiroolu pada si bo ṣe wa tẹlẹ, bo ba fẹ kijọba rẹ jẹ itẹwọgba fawon araalu bayii.
Osifo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, lẹyin ipade pataki kan bayii to waye laarin awọn oloye ẹgbẹ TUC yii niluu Abuja.
Ninu ọrọ rẹ, Osifo ni ohun kan ṣoṣo ti ajọ TUC n beere lọwọ Aarẹ Tinubu ni pe ko kọkọ da owo epo bẹntiroolu ọhun pada si bo ti ṣe wa tẹlẹ naa.
O ni, ‘Inu gbogbo awa ọmọ ẹgbẹ TUC ati awọn oloye ẹgbẹ ko dun rara si igbesẹ pajawiri ti Aarẹ Tinubu gbe nipa ọrọ epo bẹntiroolu, ki i ṣohun to daa rara, ohun to yẹ ki Aarẹ Tinubu kọkọ ṣe ni ko ṣepade pataki kan pẹlu awa oloye ẹgbẹ, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ rara.
‘Awa oloye ẹgbẹ ti ṣepade laarin ara wa, a si ti fẹnu ko bayii pe igbesẹ Aarẹ Tinubu ki i ṣohun to daa rara, a ṣetan lati jokoo ṣepade alaafia pẹlu ijọba apapọ lori ọrọ epo bẹntiroolu naa, ṣugbọn ki wọn kọkọ da owo epo bẹntiroolu naa pada si bo ti ṣe wa tẹlẹ yẹn lo daa ju, a ṣepade kan pẹlu awọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii l’Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ to kọja, a ko ti i fẹnuko sibi kankan rara, ipade naa ṣi n lọ lọwọ ni.