Ijọba apapọ kede ọjọ Aje gẹgẹ bii isinmi lẹnu iṣẹ

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ijọba apapọ orileede yii ti kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lati fi ṣeranti ayajọ ọjọ dẹmokiresi nilẹ wa.

Akọwe agba ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ kan to n ri sọrọ eto abẹle lorileede yii, Dokita Oluwatoyin Akinlade, lo sọrọ ọhun di mimo fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kejọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, niluu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ, Akinlade ki awọn eeyan orileeede yii fun ti isinmi ayajọ ọjọ dẹmokiresi  to n bọ lọna yii, o ni ijọba apapọ ti fọntẹ lu u pe ki awọn oṣiṣẹ jake-jado orileede yii wa ni isinmi fun ti ọludee naa.

O ṣapejuwe awọn oke iṣoro kọọkan ti orileede wa ti kọja ko too di pe a de ibi ta a wa bayii. O ni eyi ki i ṣe tuntun rara, nitori bawọn orileede gbogbo ta a n wo loke ṣe la tiwọn naa kọja niyẹn, ati pe ohun to ṣe koko ju lọ ni pe ki gbogbo wa ri i pe ọko oju omi ijọba dẹmokiresi ilẹ wa ko  danu, bẹẹ ni awọn ọmọ orileeede yii ko ku sinu agbami naa.

O waa rọ awọn araalu gbogbo, paapaa ju lọ awọn ti wọn nifẹẹ orileede yii daadaa pe ki wọn kun fun adura nigba gbogbo, ki ọkọ ijọba ilẹ wa le gunlẹ si ebute ayọ lopin ohun gbogbo.

Leave a Reply