Adewale Adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣepade pataki kan pẹlu awọn ọba alaye gbogbo ti wọn wa lorileede yii.
Ipade pataki ọhun to waye laarin awọn ọba alaye onipo kin-in-ni nilẹ wa lawọn ọba bii, Ọọni tile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi Ọjaja 11 ati Sultan tilẹ Ṣokoto, Alhaji Sa’ad Abubarkar 111, naa wa lara awọn ọba ti wọn ṣepade pẹlu Tinubu ninu ọkan lara awọn gbọngan igbalejo nla kan bayii to wa ninu Aso Rock, l’Abuja.
ALAROYE gbọ pe ipade ọhun bẹrẹ ni nnkan bii ago mẹwaa owurọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko gba awọn oniroyin kankan laaye lati wa nibi ipade ọhun, ALAROYE gbọ pe lara awọn koko ti wọn sọrọ le lori ni bi eto aabo yoo ṣe fẹsẹ mulẹ daadaa lorileede yii, ti ẹmi ati dukia awọn araalu yoo si de daadaa ju bo ti ṣe wa tẹlẹ lọ.
Ninu ọrọ Ọọni Ile-Ifẹ, Ẹnitan Ogunwusi, toun naa jẹ ọkan pataki lara awọn alaga ẹgbẹ awọn ọba alaye ti wọn ṣepade pẹlu Aarẹ lo ti sọ pe, ‘‘Awọn ohun kọọkan wa to jẹ pe apa awa ọba alaye gbogbo ka daadaa, lara rẹ ni eto aabo to mẹhẹ bayii. Akoko ree fawọn alaṣẹ ijọba ilẹ yii lati ṣe amulo awa ọba alaye. Ki i ṣe pe ọwọ wa dilẹ tẹlẹ rara, ṣugbọn kiṣẹ ọhun le rọrun daadaa fawọn alaṣẹ ijọba ilẹ wa, o yẹ ki wọn faaye gba wa lati ran wọn lọwọ nipa eto aabo ilẹ wa.
‘‘Ipilẹ orileede yii wa lọwọ awa ọba alaye gbogbo, awa paapaa si ti ṣetan lati fara sin orileede yii doju ami, ta a si maa ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe eto aabo fẹsẹ mulẹ daadaa lorileede yii. Ẹ ma ṣe koyan wa kere rara nipa eto abo orileede yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Sultan tilẹ Sokoto paapaa sọ pe oun ni igbagbọ ninu iṣakooso Aarẹ Tinubu lori ohun to n koju orileede yii lọwọ pe, Aarẹ ati Igbakeji rẹ yoo yanju awọn oke iṣoro naa patapata laarin ọjọ perente.
Ni ipari ọrọ rẹ, Sultan waa dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba lori bi eto idibo to gbe Aarẹ wọle ṣe lọ wọọrọwọ, ti ko sija rara laarin ilu paapaa ju lọ bawọn kan ti ṣe n sọ pe awọn ko ni i gba lae pe Aarẹ Tinubu lo wọle.
Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni Aarẹ Tinubu ṣepade pataki kan pẹlu awọn gomina atawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba gbogbo ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo niluu Abuja.